Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Matiu 8:2-10 BIBELI MIMỌ (BM)

2. Ẹnìkan tí ó ní àrùn ẹ̀tẹ̀ sì wá, ó kúnlẹ̀ níwájú rẹ̀, ó ní, “Alàgbà bí o bá fẹ́, o lè sọ ara mi di mímọ́.”

3. Jesu bá na ọwọ́ rẹ̀, ó fi kàn án, ó ní, “Mo fẹ́, kí ara rẹ di mímọ́.” Lẹsẹkẹsẹ ni àrùn ẹ̀tẹ̀ náà bá kúrò lára rẹ̀.

4. Jesu wá sọ fún un pé, “Má sọ fún ẹnikẹ́ni. Ṣugbọn, lọ, fi ara rẹ han alufaa, kí o ṣe ìrúbọ gẹ́gẹ́ bí Mose ti pa á láṣẹ, bí ẹ̀rí fún wọn pé ara rẹ ti dá.”

5. Nígbà tí Jesu wọ ìlú Kapanaumu, ọ̀gágun kan tí ó ní ọgọrun-un ọmọ-ogun lábẹ́ rẹ̀ tọ̀ ọ́ wá, ó ń bẹ̀ ẹ́; ó ní,

6. “Alàgbà, ọmọ-ọ̀dọ̀ mi kan wà ninu ilé tí àrùn ẹ̀gbà ń dà láàmú, ó sì ń joró gidigidi.”

7. Jesu bá sọ fún un pé, “N óo wá, n óo sì wò ó sàn.”

8. Ṣugbọn ọ̀gágun náà dáhùn pé, “Alàgbà, èmi kò yẹ ní ẹni tí ìwọ ìbá wọ inú ilé rẹ̀. Ṣá sọ gbolohun kan, ara ọmọ-ọ̀dọ̀ mi yóo sì dá.

9. Nítorí ẹni tí ó wà lábẹ́ àṣẹ ni èmi náà, mo ní àwọn ọmọ-ogun lábẹ́ mi. Bí mo bá sọ fún ọ̀kan pé, ‘Lọ!’ yóo lọ ni. Bí mo bá sọ fún òmíràn pé, ‘Wá!’ yóo sì wá. Bí mo bá sọ fún ẹrú mi pé, ‘Ṣe èyí!’ yóo ṣe é ni.”

10. Nígbà tí Jesu gbọ́, ẹnu yà á, ó sọ fún àwọn tí ó ń tẹ̀lé e pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, n kò rí irú igbagbọ báyìí ní Israẹli pàápàá!

Ka pipe ipin Matiu 8