Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Matiu 5:1-7 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Nígbà tí Jesu rí ọ̀pọ̀ eniyan, ó gun orí òkè lọ. Ó jókòó; àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bá lọ sọ́dọ̀ rẹ̀.

2. Ó bá tẹnu bọ̀rọ̀, ó ń kọ́ wọn pé:

3. “Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ó jẹ́ òtòṣì ní ẹ̀mí,nítorí tiwọn ni ìjọba ọ̀run.

4. Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀,nítorí Ọlọrun yóo tù wọ́n ninu.

5. Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn onírẹ̀lẹ̀,nítorí wọn yóo jogún ayé.

6. Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ebi òdodo ń pa, tí òùngbẹ òdodo sì ń gbẹ,nítorí Ọlọrun yóo bọ́ wọn ní àbọ́yó.

7. Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn aláàánú,nítorí Ọlọrun yóo ṣàánú wọn.

Ka pipe ipin Matiu 5