Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Matiu 27:34-45 BIBELI MIMỌ (BM)

34. wọ́n fún un ní ọtí kíkorò mu. Nígbà tí ó tọ́ ọ wò, ó kọ̀, kò mu ún.

35. Nígbà tí wọ́n kàn án mọ́ agbelebu tán, wọ́n pín aṣọ rẹ̀ mọ́ ara wọn lọ́wọ́, wọ́n ṣẹ́ gègé láti mọ èyí tí yóo kan ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn.

36. Wọ́n bá jókòó níbẹ̀, wọ́n ń ṣọ́ ọ.

37. Wọ́n fi àkọlé kan kọ́ sí òkè orí rẹ̀, wọ́n kọ ẹ̀sùn tí a fi kàn án sibẹ pé, “Eléyìí ni Jesu ọba àwọn Juu.”

38. Wọ́n tún kan àwọn ọlọ́ṣà meji mọ́ agbelebu pẹlu rẹ̀, ọ̀kan ní ọwọ́ ọ̀tún, ekeji ní ọwọ́ òsì rẹ̀.

39. Àwọn tí ó ń kọjá lọ ń sọ ìsọkúsọ sí i. Wọ́n ń já apá mọ́nú,

40. wọ́n ń sọ pé, “Ìwọ tí yóo wó Tẹmpili, tí yóo tún un kọ́ ní ọjọ́ mẹta, gba ara rẹ là. Bí Ọmọ Ọlọrun bá ni ọ́, sọ̀kalẹ̀ kúrò lórí agbelebu.”

41. Bákan náà ni àwọn olórí alufaa ati àwọn amòfin ati àwọn àgbà, àwọn náà ń fi í ṣe ẹlẹ́yà. Wọ́n ń sọ pé,

42. “Àwọn ẹlòmíràn ni ó rí gbà là, kò lè gba ara rẹ̀ là. Ṣé ọba Israẹli ni! Kí ó sọ̀kalẹ̀ nisinsinyii láti orí agbelebu, a óo gbà á gbọ́.

43. Ṣé ó gbẹ́kẹ̀lé Ọlọrun ni! Kí Ọlọrun gbà á sílẹ̀ nisinsinyii bí ó bá fẹ́ ẹ! Ṣebí ó sọ pé ọmọ Ọlọrun ni òun.”

44. Bákan náà ni àwọn ọlọ́ṣà tí wọ́n kàn mọ́ agbelebu pẹlu rẹ̀ fi ń ṣe ẹlẹ́yà.

45. Láti agogo mejila ọ̀sán ni òkùnkùn ti bo gbogbo ilẹ̀ títí di agogo mẹta ọ̀sán.

Ka pipe ipin Matiu 27