Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Matiu 27:25-36 BIBELI MIMỌ (BM)

25. Gbogbo àwọn eniyan náà dáhùn pé, “Kí ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wà lórí àwa ati àwọn ọmọ wa!”

26. Pilatu bá dá Baraba sílẹ̀ fún wọn. Lẹ́yìn tí ó ti pàṣẹ pé kí wọ́n na Jesu ní pàṣán, ó fi í lé wọn lọ́wọ́ láti kàn mọ̀ agbelebu.

27. Àwọn ọmọ-ogun gomina bá mú Jesu lọ sí ibùdó wọn, gbogbo wọn bá péjọ lé e lórí.

28. Wọ́n bọ́ ẹ̀wù rẹ̀, wọ́n wá fi aṣọ àlàárì bò ó lára.

29. Wọ́n fi ẹ̀gún hun adé, wọ́n fi dé e lórí. Wọ́n fi ọ̀pá sí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀. Wọ́n wá ń kúnlẹ̀ níwájú rẹ̀, wọ́n ń fi ṣe yẹ̀yẹ́; wọ́n ń wí pé, “Kabiyesi, ọba àwọn Juu.”

30. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń tutọ́ sí i lára. Wọ́n mú ọ̀pá, wọ́n ń kán an mọ́ ọn lórí.

31. Nígbà tí wọn ti fi ṣe ẹlẹ́yà tẹ́rùn, wọ́n bọ́ aṣọ àlàárì náà kúrò lára rẹ̀, wọ́n fi tirẹ̀ wọ̀ ọ́. Wọ́n bá mú un lọ láti kàn án mọ́ agbelebu.

32. Nígbà tí wọn ń jáde lọ, wọ́n rí ọkunrin kan ará Kirene tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Simoni. Wọ́n bá fi ipá mú un láti ru agbelebu Jesu.

33. Nígbà tí wọ́n dé ibi tí wọn ń pè ní Gọlgọta (ìtumọ̀ èyí tíí ṣe “Ibi Agbárí”),

34. wọ́n fún un ní ọtí kíkorò mu. Nígbà tí ó tọ́ ọ wò, ó kọ̀, kò mu ún.

35. Nígbà tí wọ́n kàn án mọ́ agbelebu tán, wọ́n pín aṣọ rẹ̀ mọ́ ara wọn lọ́wọ́, wọ́n ṣẹ́ gègé láti mọ èyí tí yóo kan ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn.

36. Wọ́n bá jókòó níbẹ̀, wọ́n ń ṣọ́ ọ.

Ka pipe ipin Matiu 27