Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Matiu 27:1-11 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, gbogbo àwọn olórí alufaa ati àwọn àgbà ìlú jọ forí-korí nípa ọ̀ràn Jesu, kí wọ́n lè pa á.

2. Wọ́n dè é, wọ́n bá fà á lọ láti fi lé Pilatu, gomina, lọ́wọ́.

3. Nígbà tí Judasi, ẹni tí ó fi Jesu fún àwọn ọ̀tá rí i pé a dá Jesu lẹ́bi, ó ronupiwada. Ó bá lọ dá ọgbọ̀n owó fadaka pada fún àwọn olórí alufaa ati àwọn àgbà.

4. Ó ní, “Mo ṣẹ̀ ní ti pé mo ṣe ikú pa aláìṣẹ̀.”Wọ́n bá dá a lóhùn pé, “Èwo ló kàn wá ninu rẹ̀? Ẹjọ́ tìrẹ ni.”

5. Judasi bá da owó náà sílẹ̀ ninu Tẹmpili, ó jáde, ó bá lọ pokùnso.

6. Àwọn olórí alufaa mú owó fadaka náà, wọ́n ní, “Kò tọ́ fún wa láti fi í sinu àpò ìṣúra Tẹmpili mọ́ nítorí owó ẹ̀jẹ̀ ni.”

7. Lẹ́yìn tí wọ́n ti forí-korí, wọ́n fi owó náà ra ilẹ̀ amọ̀kòkò fún ìsìnkú àwọn àlejò.

8. Ìdí nìyí ti a fi ń pe ilẹ̀ náà ní, “Ilẹ̀ ẹ̀jẹ̀” títí di òní olónìí.

9. Báyìí ni ohun tí wolii Jeremaya, wí ṣẹ, nígbà tí ó sọ pé, “Wọ́n mú ọgbọ̀n owó fadaka náà, iye tí a dá lé orí ẹ̀mí náà, nítorí iye tí àwọn ọmọ Israẹli ń dá lé eniyan lórí nìyí,

10. wọ́n lo owó náà fún ilẹ̀ amọ̀kòkò, gẹ́gẹ́ bí Oluwa ti pàṣẹ fún mi.”

11. Jesu bá dúró siwaju gomina. Gomina bi í pé, “Ìwọ ni ọba àwọn Juu bí?”Jesu ní, “O ti fi ẹnu ara rẹ sọ ọ́.”

Ka pipe ipin Matiu 27