Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Matiu 25:9-25 BIBELI MIMỌ (BM)

9. Àwọn ọlọ́gbọ́n dá wọn lóhùn pé, ‘Rárá o! Epo tí a ní kò tó fún àwa ati ẹ̀yin. Ẹ kúkú lọ sọ́dọ̀ àwọn tí ń ta epo, kí ẹ ra tiyín.’

10. Nígbà tí wọ́n lọ ra epo, ọkọ iyawo dé, àwọn tí wọ́n ti múra sílẹ̀ bá wọ ilé ibi igbeyawo pẹlu rẹ̀, wọ́n sì ti ìlẹ̀kùn.

11. “Ní ìgbẹ̀yìn àwọn wundia yòókù dé, wọ́n ní, ‘Alàgbà, alàgbà, ẹ ṣílẹ̀kùn fún wa!’

12. Ṣugbọn ó dá wọn lóhùn pé, ‘Rárá o! Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé èmi kò mọ̀ yín.’

13. “Nítorí náà, ẹ máa ṣọ́nà, nítorí ẹ kò mọ ọjọ́ tabi àkókò.

14. “Nígbà náà ìjọba ọ̀run yóo tún rí báyìí. Ọkunrin kan ń lọ sí ìdálẹ̀. Ó bá pe àwọn ẹrú rẹ̀, ó fi àwọn dúkìá rẹ̀ lé wọn lọ́wọ́.

15. Ó fún ọ̀kan ni àpò owó marun-un, ó fún ekeji ní àpò meji, ó fún ẹkẹta ní àpò kan. Ó fún ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn bí agbára rẹ̀ ti tó; ó bá lọ sí ìdálẹ̀.

16. Kíá, bí ó ti lọ tán, ẹni tí ó gba àpò marun-un lọ ṣòwò, ó bá jèrè àpò marun-un.

17. Bákan náà ni ẹni tí ó gba àpò meji. Òun náà jèrè àpò meji.

18. Ṣugbọn ẹni tí ó gba àpò kan lọ wa ilẹ̀, ó bá bo owó oluwa rẹ̀ mọ́lẹ̀.

19. “Lẹ́yìn ọjọ́ pípẹ́, oluwa àwọn ẹrú náà dé, ó bá bẹ̀rẹ̀ sí bi wọ́n bí wọ́n ti ṣe sí.

20. Nígbà tí ẹni tí ó gba àpò marun-un dé, ó gbé àpò marun-un mìíràn wá, ó ní, ‘Alàgbà, àpò marun-un ni o fún mi. Mo ti jèrè àpò marun-un lórí rẹ̀.’

21. Oluwa rẹ̀ wí fún un pé, ‘O ṣeun, ìwọ olóòótọ́ ẹrú, eniyan rere ni ọ́. O ti ṣe olóòótọ́ ninu nǹkan kékeré, a óo fi ọ́ ṣe alámòójútó nǹkan pupọ. Bọ́ sinu ayọ̀ oluwa rẹ.’

22. “Bẹ́ẹ̀ náà ni ẹni tí ó gba àpò meji wá, ó ní ‘Alàgbà, àpò meji ni o fún mi. Mo ti jèrè àpò meji lórí rẹ̀!’

23. Oluwa rẹ̀ sọ fún un pé, ‘O ṣeun, ìwọ olóòótọ́ ẹrú, eniyan rere ni ọ́. O ti ṣe olóòótọ́ ninu nǹkan kékeré, n óo fi ọ́ ṣe alámòójútó nǹkan pupọ. Bọ́ sinu ayọ̀ oluwa rẹ.’

24. “Lẹ́yìn náà, ẹni tí ó gba àpò kan wá, ó ní, ‘Alàgbà mo mọ̀ pé eniyan líle ni ọ́. Ibi tí o kò fúnrúgbìn sí ni o tí ń kórè. Ibi tí o kò fi nǹkan pamọ́ sí ni ò ń fojú wá a sí.

25. Ẹ̀rù rẹ bà mí, mo bá lọ fi àpò kan rẹ pamọ́ sinu ilẹ̀. Òun nìyí, gba nǹkan rẹ!’

Ka pipe ipin Matiu 25