Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Matiu 25:16-32 BIBELI MIMỌ (BM)

16. Kíá, bí ó ti lọ tán, ẹni tí ó gba àpò marun-un lọ ṣòwò, ó bá jèrè àpò marun-un.

17. Bákan náà ni ẹni tí ó gba àpò meji. Òun náà jèrè àpò meji.

18. Ṣugbọn ẹni tí ó gba àpò kan lọ wa ilẹ̀, ó bá bo owó oluwa rẹ̀ mọ́lẹ̀.

19. “Lẹ́yìn ọjọ́ pípẹ́, oluwa àwọn ẹrú náà dé, ó bá bẹ̀rẹ̀ sí bi wọ́n bí wọ́n ti ṣe sí.

20. Nígbà tí ẹni tí ó gba àpò marun-un dé, ó gbé àpò marun-un mìíràn wá, ó ní, ‘Alàgbà, àpò marun-un ni o fún mi. Mo ti jèrè àpò marun-un lórí rẹ̀.’

21. Oluwa rẹ̀ wí fún un pé, ‘O ṣeun, ìwọ olóòótọ́ ẹrú, eniyan rere ni ọ́. O ti ṣe olóòótọ́ ninu nǹkan kékeré, a óo fi ọ́ ṣe alámòójútó nǹkan pupọ. Bọ́ sinu ayọ̀ oluwa rẹ.’

22. “Bẹ́ẹ̀ náà ni ẹni tí ó gba àpò meji wá, ó ní ‘Alàgbà, àpò meji ni o fún mi. Mo ti jèrè àpò meji lórí rẹ̀!’

23. Oluwa rẹ̀ sọ fún un pé, ‘O ṣeun, ìwọ olóòótọ́ ẹrú, eniyan rere ni ọ́. O ti ṣe olóòótọ́ ninu nǹkan kékeré, n óo fi ọ́ ṣe alámòójútó nǹkan pupọ. Bọ́ sinu ayọ̀ oluwa rẹ.’

24. “Lẹ́yìn náà, ẹni tí ó gba àpò kan wá, ó ní, ‘Alàgbà mo mọ̀ pé eniyan líle ni ọ́. Ibi tí o kò fúnrúgbìn sí ni o tí ń kórè. Ibi tí o kò fi nǹkan pamọ́ sí ni ò ń fojú wá a sí.

25. Ẹ̀rù rẹ bà mí, mo bá lọ fi àpò kan rẹ pamọ́ sinu ilẹ̀. Òun nìyí, gba nǹkan rẹ!’

26. “Olúwa rẹ̀ dá a lóhùn pé, ‘Ìwọ olubi ati onímẹ̀ẹ́lẹ́ ẹrú yìí. O mọ̀ pé èmi a máa kórè níbi tí n kò fúnrúgbìn sí, ati pé èmi a máa fojú wá nǹkan níbi tí n kò fi pamọ́ sí.

27. Nígbà tí o mọ̀ bẹ́ẹ̀, kí ni kò jẹ́ kí o fi owó mi fún àwọn agbowó-pamọ́ pé nígbà tí mo bá dé, kí n lè gba owó mi pada pẹlu èlé?

28. Nítorí náà, ẹ gba àpò kan náà lọ́wọ́ rẹ̀, kí ẹ fún ẹni tí ó ní àpò mẹ́wàá.

29. Nítorí ẹni tí ó bá ní, òun ni a óo túbọ̀ fún, kí ó lè ní sí i. Lọ́wọ́ ẹni tí kò ní ni a óo sì ti gba ìwọ̀nba díẹ̀ tí ó ní.

30. Kí ẹ mú ẹrú tí kò wúlò yìí kí ẹ tì í sinu òkùnkùn biribiri. Níbẹ̀ ni ẹkún ati ìpayínkeke yóo wà.’

31. “Nígbà tí Ọmọ-Eniyan bá yọ ninu ìgúnwà rẹ̀ pẹlu gbogbo àwọn angẹli, nígbà náà ni yóo jókòó lórí ìtẹ́ ògo rẹ̀.

32. Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yóo péjọ níwájú rẹ̀, yóo wá yà wọ́n sọ́tọ̀ọ̀tọ̀, bí olùṣọ́-aguntan tíí ya àwọn aguntan sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn ewúrẹ́.

Ka pipe ipin Matiu 25