Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Matiu 25:1-9 BIBELI MIMỌ (BM)

1. “Ní àkókò náà, ọ̀rọ̀ ìjọba ọ̀run yóo dàbí ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí àwọn wundia mẹ́wàá, tí wọn gbé àtùpà wọn láti jáde lọ pàdé ọkọ iyawo.

2. Marun-un ninu wọn jẹ́ òmùgọ̀, marun-un sì jẹ́ ọlọ́gbọ́n.

3. Àwọn òmùgọ̀ gbé àtùpà, ṣugbọn wọn kò gbé epo lọ́wọ́.

4. Àwọn ọlọ́gbọ́n rọ epo sinu ìgò, wọ́n gbé e lọ́wọ́ pẹlu àtùpà wọn.

5. Nígbà tí ọkọ iyawo pẹ́ kí ó tó dé, gbogbo wọn bẹ̀rẹ̀ sí tòògbé, wọ́n bá sùn lọ.

6. “Nígbà tí ó di ààrin ọ̀gànjọ́, igbe ta pé, ‘Ọkọ iyawo dé! Ẹ jáde lọ pàdé rẹ̀.’

7. Nígbà náà ni gbogbo àwọn wundia náà tají, wọ́n tún iná àtùpà wọn ṣe.

8. Àwọn wundia òmùgọ̀ wá bẹ̀rẹ̀ sí bẹ àwọn ọlọ́gbọ́n pé, ‘Ẹ jọ̀wọ́ ẹ fún wa ninu epo yín, nítorí àtùpà wa ń kú lọ.’

9. Àwọn ọlọ́gbọ́n dá wọn lóhùn pé, ‘Rárá o! Epo tí a ní kò tó fún àwa ati ẹ̀yin. Ẹ kúkú lọ sọ́dọ̀ àwọn tí ń ta epo, kí ẹ ra tiyín.’

Ka pipe ipin Matiu 25