Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Matiu 24:6-17 BIBELI MIMỌ (BM)

6. Àkókò ń bọ̀ tí ẹ óo gbúròó ogun ati ìrọ́kẹ̀kẹ̀ ogun. Ẹ má bẹ̀rù. Èyí níláti rí bẹ́ẹ̀, ṣugbọn kò ì tíì tó àkókò tí òpin ayé yóo dé.

7. Nítorí orílẹ̀-èdè yóo dìde sí orílẹ̀-èdè; ìjọba yóo dìde sí ìjọba. Ìyàn yóo mú. Ilẹ̀ yóo máa mì ní ọpọlọpọ ìlú.

8. Ìbẹ̀rẹ̀ ìrora bíi ti ìrọbí ni gbogbo èyí.

9. “Ní àkókò náà, wọn yóo fà yín lé àwọn eniyan lọ́wọ́ pé kí wọ́n jẹ yín níyà, kí wọ́n sì pa yín. Gbogbo ará ayé ni yóo kórìíra yín nítorí orúkọ mi.

10. Ọpọlọpọ yóo kùnà ninu igbagbọ; wọn yóo tú àwọn mìíràn fó; wọn yóo sì kórìíra àwọn mìíràn.

11. Ọpọlọpọ àwọn wolii èké ni yóo dìde, wọn yóo tan ọpọlọpọ jẹ.

12. Nítorí pé ìwà ìbàjẹ́ yóo gbilẹ̀, ìfẹ́ ọpọlọpọ yóo rẹ̀wẹ̀sì.

13. Ṣugbọn ẹni tí ó bá forí tì í títí dé òpin, òun ni a óo gbà là.

14. A óo waasu ìyìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ayé gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí sí gbogbo orílẹ̀-èdè. Lẹ́yìn náà ni òpin yóo dé.

15. “Nígbà náà ni ẹ óo rí ohun ẹ̀gbin tí wolii Daniẹli ti sọ tẹ́lẹ̀, tí ó dúró ní ibi mímọ́ (ìwọ olùkàwé yìí, jẹ́ kí ohun tí ò ń kà yé ọ).

16. Tí èyí bá ti ṣẹlẹ̀, kí àwọn tí ó wà ní Judia sálọ sí orí òkè.

17. Ẹni tí ó wà lókè pẹ̀tẹ́ẹ̀sì kò gbọdọ̀ sọ̀kalẹ̀ wọlé lọ mú àwọn ohun ìní rẹ̀.

Ka pipe ipin Matiu 24