Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Matiu 24:42-50 BIBELI MIMỌ (BM)

42. “Nítorí náà, ẹ máa ṣọ́nà, nítorí ẹ kò mọ ọjọ́ tí Oluwa yín ń bọ̀.

43. Ẹ mọ èyí pé bí baálé bá mọ àsìkò tí olè yóo dé, ìbá máa ṣọ́nà, kì bá tí jẹ́ kí olè kó ilé rẹ̀.

44. Nítorí náà, kí ẹ̀yin náà wà ní ìmúrasílẹ̀, nítorí ní wakati tí ẹ kò rò tẹ́lẹ̀ ni Ọmọ-Eniyan yóo dé.

45. “Bí ẹrú kan bá jẹ́ olóòótọ́ ati ọlọ́gbọ́n, ọ̀gá rẹ̀ á fi ilé rẹ̀ lé e lọ́wọ́, pé kí ó máa fún àwọn eniyan ní oúnjẹ lásìkò.

46. Ayọ̀ ń bẹ fún ẹrú náà tí ọ̀gá rẹ̀ bá bá a lẹ́nu iṣẹ́ rẹ̀.

47. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé yóo fi í ṣe olùtọ́jú ohun gbogbo tí ó ní.

48. Ṣugbọn bí ẹrú bá jẹ́ olubi, tí ó bá rò ní ọkàn rẹ̀ pé, ‘Ọ̀gá mi kò ní tètè dé!’

49. Tí ó wá bẹ̀rẹ̀ sí lu àwọn ẹrú, ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, tí ó ń jẹ, tí ó ń mu pẹlu àwọn ọ̀mùtí,

50. ọ̀gá ẹrú náà yóo dé ní ọjọ́ tí kò rò, ati ní wakati tí kò lérò.

Ka pipe ipin Matiu 24