Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Matiu 23:1-10 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Jesu bá sọ fún àwọn eniyan ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé,

2. “Àwọn amòfin ati àwọn Farisi ni olùtúmọ̀ òfin Mose.

3. Nítorí náà, ohun gbogbo tí wọ́n bá sọ fun yín ni kí ẹ ṣe. Ṣugbọn ẹ má ṣe tẹ̀lé ìwà wọn, nítorí ọ̀tọ̀ ni ohun tí wọn óo sọ, ọ̀tọ̀ ni ohun tí wọn óo ṣe.

4. Wọn á di ẹrù wúwo, wọn á gbé e ka àwọn eniyan lórí, bẹ́ẹ̀ ni àwọn fúnra wọn kò sì jẹ́ fi ọwọ́ wọn kan ẹrù náà.

5. Gbogbo ohun tí wọn ń ṣe, wọ́n ń ṣe é kí eniyan lè rí wọn ni. Wọn á di tírà pàlàbà-pàlàbà mọ́ iwájú. Wọn á ṣe waja-waja ńláńlá sí etí aṣọ wọn.

6. Wọ́n fẹ́ràn ìjókòó ọlá níbi àsè. Wọ́n fẹ́ràn àga iwájú ní ilé ìpàdé.

7. Wọ́n fẹ́ràn kí eniyan máa kí wọn láàrin ọjà ati kí àwọn eniyan máa pè wọ́n ní ‘Olùkọ́ni.’

8. Ṣugbọn ẹ̀yin ní tiyín, ẹ má jẹ́ kí wọ́n pè yín ní ‘Olùkọ́ni,’ nítorí ẹnìkan ṣoṣo ni olùkọ́ni yín; arakunrin ni gbogbo yín jẹ́.

9. Ẹ má pe ẹnìkan ní ‘Baba’ ní ayé, nítorí ẹnìkan ṣoṣo ni Baba yín, ẹni tí ó wà ní ọ̀run.

10. Bẹ́ẹ̀ ni ẹ má jẹ́ kí ẹnikẹ́ni pè yín ní ‘Ọ̀gá,’ nítorí ọ̀gá kanṣoṣo ni ẹ ní, òun ni Mesaya.

Ka pipe ipin Matiu 23