Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Matiu 22:28-46 BIBELI MIMỌ (BM)

28. Tí ó bá di àkókò ajinde, ninu àwọn mejeeje, iyawo ta ni obinrin náà yóo jẹ́, nígbà tí ó jẹ́ pé gbogbo wọn ni wọ́n ti fi ṣe aya?”

29. Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ẹ ṣìnà, nítorí pé ẹ kò mọ Ìwé Mímọ́ ati agbára Ọlọrun.

30. Nítorí pé ní àkókò ajinde kò ní sí pé à ń gbé iyawo, tabi pé à ń fi ọmọ fún ọkọ; nítorí bí àwọn angẹli ti rí ní ọ̀run ni wọn yóo rí.

31. Nípa ti ajinde àwọn òkú, ẹ kò ì tíì ka ọ̀rọ̀ tí Ọlọrun sọ fun yín pé,

32. ‘Èmi ni Ọlọrun Abrahamu, Ọlọrun Isaaki ati Ọlọrun Jakọbu.’ Ọlọrun kì í ṣe Ọlọrun àwọn òkú, Ọlọrun àwọn alààyè ni.”

33. Nígbà tí àwọn eniyan gbọ́, ẹnu yà wọ́n sí ẹ̀kọ́ rẹ̀.

34. Nígbà tí àwọn Farisi gbọ́ pé ó ti pa àwọn Sadusi lẹ́nu mọ́, wọ́n kó ara wọn jọ.

35. Ọ̀kan ninu wọn tí ó jẹ́ amòfin, bi í ní ìbéèrè kan láti fi dẹ ẹ́, pé,

36. “Olùkọ́ni, òfin wo ni ó ṣe pataki jùlọ ninu Ìwé Òfin?”

37. Jesu dá a lóhùn pé, “ ‘Fẹ́ Oluwa Ọlọrun rẹ pẹlu gbogbo ọkàn rẹ, ati gbogbo ẹ̀mí rẹ, ati ní gbogbo èrò rẹ.’

38. Èyí ni òfin tí ó ga jùlọ, òun sì ni ekinni.

39. Ekeji fi ara jọ ọ́: ‘Fẹ́ràn ọmọnikeji rẹ bí o ti fẹ́ ara rẹ.’

40. Òfin mejeeji wọnyi ni gbogbo òfin ìyókù ati ọ̀rọ̀ inú ìwé àwọn wolii rọ̀ mọ́.”

41. Nígbà tí àwọn Farisi péjọ pọ̀, Jesu bi wọ́n pé,

42. “Kí ni ẹ rò nípa Mesaya, ọmọ ta ni?”Wọ́n dá a lóhùn pé, “Ọmọ Dafidi ni.”

43. Ó bá tún bi wọ́n pé, “Bí ó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, báwo ni Ẹ̀mí Mímọ́ ṣe darí Dafidi tí Dafidi fi pe Mesaya ní ‘Oluwa’? Dafidi sọ pé,

44. ‘OLUWA sọ fún Oluwa mi pé:Jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mitítí n óo fi sọ àwọn ọ̀tá rẹ di ohun ìtìsẹ̀ rẹ.’

45. Bí Dafidi bá pè é ní ‘OLUWA’, báwo ni Mesaya ti ṣe jẹ́ ọmọ rẹ̀?”

46. Kò sí ẹnìkan tí ó lè dá a lóhùn ọ̀rọ̀ yìí. Láti ọjọ́ náà, ẹnikẹ́ni kò ní ìgboyà láti tún bi í ní ohunkohun mọ́.

Ka pipe ipin Matiu 22