Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Matiu 22:24-39 BIBELI MIMỌ (BM)

24. “Olùkọ́ni, Mose sọ pé bí ẹnìkan bá kú láì ní ọmọ, kí àbúrò rẹ̀ fẹ́ aya rẹ̀ kí ó lè bí ọmọ fún ẹ̀gbọ́n rẹ̀.

25. Àwọn tẹ̀gbọ́n-tàbúrò meje kan wà lọ́dọ̀ wa. Ekinni gbé iyawo, láìpẹ́ ó kú. Nígbà tí kò bí ọmọ, ó fi iyawo rẹ̀ sílẹ̀ fún àbúrò rẹ̀.

26. Ekeji náà kú, ati ẹkẹta, títí tí àwọn mejeeje fi kú.

27. Ní ìkẹyìn gbogbo wọn, obinrin náà wá kú.

28. Tí ó bá di àkókò ajinde, ninu àwọn mejeeje, iyawo ta ni obinrin náà yóo jẹ́, nígbà tí ó jẹ́ pé gbogbo wọn ni wọ́n ti fi ṣe aya?”

29. Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ẹ ṣìnà, nítorí pé ẹ kò mọ Ìwé Mímọ́ ati agbára Ọlọrun.

30. Nítorí pé ní àkókò ajinde kò ní sí pé à ń gbé iyawo, tabi pé à ń fi ọmọ fún ọkọ; nítorí bí àwọn angẹli ti rí ní ọ̀run ni wọn yóo rí.

31. Nípa ti ajinde àwọn òkú, ẹ kò ì tíì ka ọ̀rọ̀ tí Ọlọrun sọ fun yín pé,

32. ‘Èmi ni Ọlọrun Abrahamu, Ọlọrun Isaaki ati Ọlọrun Jakọbu.’ Ọlọrun kì í ṣe Ọlọrun àwọn òkú, Ọlọrun àwọn alààyè ni.”

33. Nígbà tí àwọn eniyan gbọ́, ẹnu yà wọ́n sí ẹ̀kọ́ rẹ̀.

34. Nígbà tí àwọn Farisi gbọ́ pé ó ti pa àwọn Sadusi lẹ́nu mọ́, wọ́n kó ara wọn jọ.

35. Ọ̀kan ninu wọn tí ó jẹ́ amòfin, bi í ní ìbéèrè kan láti fi dẹ ẹ́, pé,

36. “Olùkọ́ni, òfin wo ni ó ṣe pataki jùlọ ninu Ìwé Òfin?”

37. Jesu dá a lóhùn pé, “ ‘Fẹ́ Oluwa Ọlọrun rẹ pẹlu gbogbo ọkàn rẹ, ati gbogbo ẹ̀mí rẹ, ati ní gbogbo èrò rẹ.’

38. Èyí ni òfin tí ó ga jùlọ, òun sì ni ekinni.

39. Ekeji fi ara jọ ọ́: ‘Fẹ́ràn ọmọnikeji rẹ bí o ti fẹ́ ara rẹ.’

Ka pipe ipin Matiu 22