Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Matiu 22:15-31 BIBELI MIMỌ (BM)

15. Àwọn Farisi bá lọ forí-korí wọ́n ń wá ọ̀nà tí wọn yóo fi ká ọ̀rọ̀ mọ́ Jesu lẹ́nu.

16. Wọ́n bá rán àwọn ọmọ-ẹ̀yìn wọn pẹlu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Hẹrọdu láti bi í pé, “Olùkọ́ni, a mọ̀ pé olóòótọ́ ni ọ́, ati pé pẹlu òtítọ́ ni o fi ń kọ́ eniyan ní ọ̀nà Ọlọrun; o kì í ṣe ojuṣaaju fún ẹnikẹ́ni nítorí o kì í wojú eniyan kí o tó sọ̀rọ̀.

17. Nítorí náà sọ ohun tí o rò fún wa. Ó tọ̀nà láti san owó-orí fún Kesari ni, àbí kò tọ̀nà?”

18. Ṣugbọn Jesu mọ èrò ibi tí ó wà lọ́kàn wọn. Ó ní, “Kí ló dé tí ẹ fi ń dẹ mí ẹ̀yin alárèékérekè yìí?

19. Ẹ fi owó tí ẹ fi ń san owó-orí hàn mí.”Wọ́n bá mú owó fadaka kan fún un.

20. Ó wá bi wọ́n pé, “Àwòrán ati àkọlé ta ni èyí?”

21. Wọ́n dá a lóhùn pé, “Ti Kesari ni.”Ó bá sọ fún wọn pé, “Tí ó bá rí bẹ́ẹ̀, ẹ fi ohun tí ó jẹ́ ti Kesari fún Kesari, kí ẹ sì fi ohun tíí ṣe ti Ọlọrun fún Ọlọrun.”

22. Nígbà tí wọ́n gbọ́ báyìí, ẹnu yà wọ́n, wọ́n bá fi í sílẹ̀, wọ́n sì bá tiwọn lọ.

23. Ní ọjọ́ náà, àwọn Sadusi kan wá sọ́dọ̀ rẹ̀. (Àwọn Sadusi ni wọ́n sọ pé kò sí ajinde.) Wọ́n bi í pé,

24. “Olùkọ́ni, Mose sọ pé bí ẹnìkan bá kú láì ní ọmọ, kí àbúrò rẹ̀ fẹ́ aya rẹ̀ kí ó lè bí ọmọ fún ẹ̀gbọ́n rẹ̀.

25. Àwọn tẹ̀gbọ́n-tàbúrò meje kan wà lọ́dọ̀ wa. Ekinni gbé iyawo, láìpẹ́ ó kú. Nígbà tí kò bí ọmọ, ó fi iyawo rẹ̀ sílẹ̀ fún àbúrò rẹ̀.

26. Ekeji náà kú, ati ẹkẹta, títí tí àwọn mejeeje fi kú.

27. Ní ìkẹyìn gbogbo wọn, obinrin náà wá kú.

28. Tí ó bá di àkókò ajinde, ninu àwọn mejeeje, iyawo ta ni obinrin náà yóo jẹ́, nígbà tí ó jẹ́ pé gbogbo wọn ni wọ́n ti fi ṣe aya?”

29. Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ẹ ṣìnà, nítorí pé ẹ kò mọ Ìwé Mímọ́ ati agbára Ọlọrun.

30. Nítorí pé ní àkókò ajinde kò ní sí pé à ń gbé iyawo, tabi pé à ń fi ọmọ fún ọkọ; nítorí bí àwọn angẹli ti rí ní ọ̀run ni wọn yóo rí.

31. Nípa ti ajinde àwọn òkú, ẹ kò ì tíì ka ọ̀rọ̀ tí Ọlọrun sọ fun yín pé,

Ka pipe ipin Matiu 22