Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Matiu 2:19-23 BIBELI MIMỌ (BM)

19. Lẹ́yìn tí Hẹrọdu ti kú, angẹli Oluwa kan fara han Josẹfu ní ojú àlá ní Ijipti.

20. Ó sọ fún un pé, “Dìde, gbé ọmọ náà ati ìyá rẹ́, kí o pada lọ sí ilẹ̀ Israẹli, nítorí àwọn tí wọ́n fẹ́ pa ọmọ náà ti kú.”

21. Josẹfu bá dìde, ó gbé ọmọ náà ati ìyá rẹ̀ pada sí ilẹ̀ Israẹli.

22. Nígbà tí Josẹfu gbọ́ pé Akelau ni ó jọba ní Judia ní ipò Hẹrọdu baba rẹ̀, ẹ̀rù bà á láti lọ sibẹ. Lẹ́yìn tí a ti kìlọ̀ fún un lójú àlá, ó yẹra níbẹ̀ lọ sí agbègbè Galili.

23. Ó bá ń gbé ìlú kan tí à ń pé ní Nasarẹti. Èyí rí bẹ́ẹ̀ kí ọ̀rọ̀ tí àwọn wolii sọ lè ṣẹ pé, “A óo pè é ní ará Nasarẹti.”

Ka pipe ipin Matiu 2