Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Matiu 2:1-12 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Nígbà tí wọ́n bí Jesu ní Bẹtilẹhẹmu ní ilẹ̀ Judia, ní ayé Hẹrọdu ọba, àwọn amòye kan wá sí Jerusalẹmu láti ìhà ìlà oòrùn.

2. Wọ́n bèèrè pé, “Níbo ni ọmọ tí a bí tí yóo jẹ ọba àwọn Juu wà? A ti rí ìràwọ̀ rẹ̀ ní ìlà oòrùn, nítorí náà ni a ṣe wá láti júbà rẹ̀.”

3. Nígbà tí Hẹrọdu gbọ́, ara rẹ̀ kò balẹ̀, ara gbogbo eniyan ìlú Jerusalẹmu náà kò sì balẹ̀.

4. Ọba bá pe gbogbo àwọn olórí alufaa ati àwọn amòfin láàrin àwọn eniyan, ó wádìí nípa ibi tí a óo ti bí Kristi lọ́wọ́ wọn.

5. Wọ́n sọ fún un pé, “Ní Bẹtilẹhẹmu ti ilẹ̀ Judia ni. Nítorí bẹ́ẹ̀ ni ó wà ní àkọsílẹ̀ wolii nì pé.

6. ‘Àní ìwọ Bẹtilẹhẹmu ilẹ̀ Juda,o kì í ṣe ìlú tí ó rẹ̀yìn jùlọ ninu àwọn olú-ìlú Juda.Nítorí láti inú rẹ ni aṣiwaju kan yóo ti jáde,tí yóo jẹ́ olùṣọ́-aguntan fún Israẹli, eniyan mi.’ ”

7. Hẹrọdu bá pe àwọn amòye náà síkọ̀kọ̀, ó fọgbọ́n wádìí àkókò tí ìràwọ̀ náà yọ lọ́dọ̀ wọn.

8. Ó bá rán wọn lọ sí Bẹtilẹhẹmu. Ó ní, “Ẹ lọ, kí ẹ fẹ̀sọ̀ wádìí nípa ọmọ náà. Nígbà tí ẹ bá rí i, ẹ wá ròyìn fún mi kí èmi náà lè lọ júbà rẹ̀.”

9. Nígbà tí wọn gbọ́ ọ̀rọ̀ ọba, wọ́n lọ. Bí wọ́n ti ń lọ, ìràwọ̀ tí wọ́n ti rí ní ìlà oòrùn bẹ̀rẹ̀ sí lọ níwájú wọn títí ó fi dúró ní ọ̀gangan ibi tí ọmọ náà wà.

10. Nígbà tí wọ́n rí ìràwọ̀ náà, inú wọn dùn gan-an.

11. Bí wọ́n ti wọlé, wọ́n rí ọmọ náà pẹlu Maria ìyá rẹ̀, wọ́n kúnlẹ̀, wọ́n sì júbà rẹ̀. Wọ́n ṣí àpótí ìṣúra wọn, wọ́n fún un ní ẹ̀bùn: wúrà, turari ati òjíá.

12. Nítorí pé Ọlọrun ti kìlọ̀ fún wọn tẹ́lẹ̀ ní ojú àlá, wọn kò pada sọ́dọ̀ Hẹrọdu mọ́; ọ̀nà mìíràn ni wọ́n gbà pada lọ sí ìlú wọn.

Ka pipe ipin Matiu 2