Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Matiu 19:19-30 BIBELI MIMỌ (BM)

19. Bọ̀wọ̀ fún baba ati ìyá rẹ. Ati pé, fẹ́ràn ẹnìkejì rẹ bí ara rẹ.”

20. Ọdọmọkunrin náà sọ fún Jesu pé, “Gbogbo òfin wọnyi ni mo ti pamọ́. Kí ni ó tún kù kí n ṣe?”

21. Jesu sọ fún un pé, “Bí o bá fẹ́ ṣe àṣepé, lọ ta dúkìá rẹ, kí o pín owó rẹ̀ fún àwọn talaka; o óo sì ní ìṣúra ní ọ̀run. Lẹ́yìn náà, máa tẹ̀lé mi.”

22. Nígbà tí ọdọmọkunrin náà gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ó kúrò níbẹ̀ pẹlu ìbànújẹ́ nítorí ó ní ọrọ̀ pupọ.

23. Jesu bá sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé yóo ṣòro fún ọlọ́rọ̀ láti wọ ìjọba ọ̀run.

24. Mo tún ń wí fun yín pé yóo rọrùn fún ràkúnmí láti wọ ojú abẹ́rẹ́ jù fún ọlọ́rọ̀ láti wọ ìjọba Ọlọrun lọ.”

25. Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ gbọ́, ẹnu yà wọ́n pupọ. Wọ́n ní, “Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, ta ni yóo rí ìgbàlà?”

26. Jesu wò wọ́n lójú, ó sọ fún wọn pé, “Èyí kò ṣeéṣe fún eniyan; ṣugbọn ohun gbogbo ni ó ṣeéṣe fún Ọlọrun.”

27. Peteru bá bi í pé, “Wò ó, àwa ti fi ilé ati ọ̀nà sílẹ̀, a wá ń tẹ̀lé ọ. Kí ni yóo jẹ́ èrè wa?”

28. Jesu sọ fún wọn pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, nígbà tí ó bá di àkókò àtúndá ayé, tí Ọmọ-Eniyan bá jókòó lórí ìtẹ́ ìgúnwà rẹ̀, ẹ̀yin náà tí ẹ tẹ̀lé mi yóo jókòó lórí ìtẹ́ mejila, ẹ óo máa ṣe ìdájọ́ lórí ẹ̀yà Israẹli mejila.

29. Gbogbo ẹni tí ó bá sì fi ilé tabi arakunrin tabi arabinrin, baba tabi ìyá, ọmọ tabi ilẹ̀ sílẹ̀, nítorí orúkọ mi, yóo gba ìlọ́po-ìlọ́po ní ọ̀nà ọgọrun-un, yóo sì tún jogún ìyè ainipẹkun.

30. Ọpọlọpọ tí ó jẹ́ ará iwájú yóo di èrò ẹ̀yìn; àwọn èrò ẹ̀yìn yóo di ará iwájú.

Ka pipe ipin Matiu 19