Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Matiu 18:1-15 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ní àkókò náà àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n bi í pé, “Ta ní ṣe pataki jùlọ ní ìjọba ọ̀run?”

2. Jesu bá pe ọmọde kan, ó mú un dúró láàrin wọn,

3. ó ní, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, bí ẹ kò bá yipada kí ẹ dàbí àwọn ọmọde, ẹ kò ní wọ ìjọba ọ̀run.

4. Nítorí náà ẹni tí ó bá rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ bí ọmọde yìí, òun ni ó jẹ́ eniyan pataki jùlọ ní ìjọba ọ̀run.

5. Ẹni tí ó bá gba ọ̀kan ninu irú àwọn ọmọde wọnyi ní orúkọ mi, èmi ni ó gbà.

6. “Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́ ohun ìkọsẹ̀ fún ọ̀kan ninu àwọn kéékèèké wọnyi tí ó gbà mí gbọ́, ó sàn fún un kí á so ọlọ ńlá mọ́ ọn lọ́rùn, kí á sọ ọ́ sinu ibú òkun.

7. Ìdájọ́ ńlá ń bẹ fún ayé, nítorí àwọn ohun ìkọsẹ̀. Dandan ni kí àwọn ohun ìkọsẹ̀ dé, ṣugbọn ẹnikẹ́ni tí ohun ìkọsẹ̀ bá ti ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá, ó gbé!

8. “Bí ọwọ́ tabi ẹsẹ̀ rẹ bá mú ọ kọsẹ̀, gé e sọnù. Ó sàn fún ọ kí o wọ inú ìyè pẹlu àbùkù ọwọ́ tabi ti ẹsẹ̀, jù pé kí o ní ọwọ́ meji tabi ẹsẹ̀ meji kí á sọ ọ́ sinu iná àjóòkú lọ.

9. Bí ojú rẹ bá mú ọ kọsẹ̀ yọ ọ́ sọnù. Ó sàn fún ọ kí o wọ inú ìyè pẹlu ojú kan jù pé kí o ní ojú meji kí á sọ ọ́ sinu iná ọ̀run àpáàdì lọ.

10. “Ẹ ṣọ́ra kí ẹ má ṣe fi ojú tẹmbẹlu ọ̀kan ninu àwọn kékeré wọnyi; nítorí mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé, àwọn angẹli wọn ní ọ̀run ń wo ojú Baba mi tí ń bẹ lọ́run nígbà gbogbo. [

11. Nítorí Ọmọ-Eniyan wá láti gba àwọn tí ó ti sọnù là.]

12. “Kí ni ẹ rò? Bí ọkunrin kan bá ní ọgọrun-un aguntan, tí ọ̀kan ninu wọn bá sọnù, ǹjẹ́ ọkunrin náà kò ní fi aguntan mọkandinlọgọrun-un yòókù sílẹ̀ lórí òkè, kí ó lọ wá èyí tí ó sọnù?

13. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, nígbà tí ó bá rí i, inú rẹ̀ yóo dùn sí i ju àwọn mọkandinlọgọrun-un tí kò sọnù lọ.

14. Bẹ́ẹ̀ gan-an ni, kì í ṣe ìfẹ́ Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run pé kí ọ̀kan ninu àwọn kékeré wọnyi kí ó ṣègbé.

15. “Bí arakunrin rẹ bá ṣẹ̀ ọ́, tètè lọ bá a sọ̀rọ̀, ìwọ rẹ̀ meji péré. Bí ó bá gbà sí ọ lẹ́nu, o ti tún sọ ọ́ di arakunrin rẹ tòótọ́.

Ka pipe ipin Matiu 18