Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Matiu 14:29-36 BIBELI MIMỌ (BM)

29. Jesu bá sọ fún un pé, “Máa bọ̀!” Ni Peteru bá sọ̀kalẹ̀ ninu ọkọ̀, ó rìn lójú omi lọ sọ́dọ̀ Jesu.

30. Ṣugbọn nígbà tí ó rí i tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́, ẹ̀rù bà á, ó bá bẹ̀rẹ̀ sí rì. Ó bá kígbe pé, “Oluwa, gbà mí!”

31. Lẹsẹkẹsẹ Jesu bá fà á lọ́wọ́, ó sọ fún un pé, “Ìwọ onigbagbọ kékeré yìí! Kí ni ó mú ọ ṣe iyè meji?”

32. Bí wọ́n ti wọ inú ọkọ́ ni afẹ́fẹ́ bá rọlẹ̀.

33. Àwọn tí ó wà ninu ọkọ̀ júbà rẹ̀, wọ́n ń sọ pé, “Lóòótọ́, Ọmọ Ọlọrun ni ọ́!”

34. Lẹ́yìn tí wọ́n ti gúnlẹ̀, wọ́n dé ilẹ̀ Genesarẹti.

35. Àwọn eniyan ibẹ̀ ti dá a mọ̀, wọ́n bá ranṣẹ lọ sí gbogbo agbègbè ibẹ̀; wọ́n gbé gbogbo àwọn tí ara wọn kò dá wá sọ́dọ̀ rẹ̀.

36. Wọ́n ń bẹ̀ ẹ́ pé kí wọn sá lè fi ọwọ́ kan etí ẹ̀wù rẹ̀. Gbogbo àwọn tí wọ́n fi ọwọ́ kàn án ni ó mú lára dá.

Ka pipe ipin Matiu 14