Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Matiu 14:20-29 BIBELI MIMỌ (BM)

20. Gbogbo wọn jẹ, wọ́n yó, àjẹkù sì kún apẹ̀rẹ̀ mejila.

21. Àwọn eniyan tí ó jẹun tó ẹgbẹẹdọgbọn (5,000) ọkunrin láì ka àwọn obinrin ati àwọn ọmọde.

22. Lẹsẹkẹsẹ, ó bẹ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọn wọ ọkọ̀ ojú omi ṣáájú òun lọ sí òdìkejì, nígbà tí ó ń tú àwọn eniyan ká.

23. Nígbà tí ó tú wọn ká tán, ó gun orí òkè lọ gbadura, òun nìkan. Nígbà tí alẹ́ lẹ́, òun nìkan ni ó wà níbẹ̀.

24. Ọkọ̀ ti kúrò ní èbúté, ó ti bọ́ sí agbami. Ìgbì omi wá ń dààmú ọkọ̀, nítorí afẹ́fẹ́ ṣọwọ́ òdì sí wọn.

25. Nígbà tí ó di nǹkan bí agogo mẹta òru, Jesu ń bọ̀ lọ́dọ̀ wọn, ó ń rìn lójú omi òkun.

26. Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rí i tí ó ń rìn lójú omi, ẹ̀rù bà wọ́n gan-an, wọ́n ń sọ pé, “Iwin ni!” Wọ́n bá kígbe, nítorí ẹ̀rù bà wọ́n.

27. Lẹsẹkẹsẹ Jesu sọ fún wọn pé, “Ẹ ṣe ara gírí. Èmi ni. Ẹ má bẹ̀rù!”

28. Peteru sọ fún un pé, “Oluwa, bí ó bá jẹ́ pé ìwọ ni, sọ pé kí n máa rìn bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ lójú omi.”

29. Jesu bá sọ fún un pé, “Máa bọ̀!” Ni Peteru bá sọ̀kalẹ̀ ninu ọkọ̀, ó rìn lójú omi lọ sọ́dọ̀ Jesu.

Ka pipe ipin Matiu 14