Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Maku 9:42-50 BIBELI MIMỌ (BM)

42. “Ẹnikẹ́ni tí ó bá mú ọ̀kan ninu àwọn kéékèèké wọnyi tí ó gbà mí gbọ́ kọsẹ̀, ó sàn fún un kí á so ọlọ ńlá mọ́ ọn lọ́rùn, kí á gbé e sọ sinu òkun.

43. Bí ọwọ́ rẹ bá mú ọ kọsẹ̀, gé e sọnù, ó sàn fún ọ kí o wọ inú ìyè pẹlu àléébù ara, jù pé kí o ní ọwọ́ mejeeji kí o wọ iná àjóòkú, [

44. níbi tí ìdin wọn kì í kú, tí iná ibẹ̀ kì í sì í kú.]

45. Bí ẹsẹ̀ rẹ bá mú ọ kọsẹ̀, gé e sọnù, ó sàn fún ọ kí o jẹ́ ẹlẹ́sẹ̀ kan kí o sì wọ inú ìyè jù pé kí o ní ẹsẹ̀ mejeeji kí á sì sọ ọ́ sinu iná, [

46. níbi tí ìdin wọn kì í kú, tí iná ibẹ̀ kì í sì í kú.]

47. Bí ojú rẹ bá mú ọ kọsẹ̀, yọ ọ́ sọnù, ó sàn fún ọ kí o wọ ìjọba Ọlọrun pẹlu ojú kan jù pé kí o ní ojú mejeeji kí a sì sọ ọ́ sinu iná,

48. níbi tí ìdin wọn kì í kú, tí iná ibẹ̀ kì í sì í kú.

49. “Iyọ̀ níí sọ ẹbọ di mímọ́, bẹ́ẹ̀ gan-an ni ó jẹ́ pé iná ni a óo fi sọ gbogbo eniyan di mímọ́.

50. “Iyọ̀ dára, ṣugbọn bí iyọ̀ bá di òbu, báwo ni yóo ṣe tún lè dùn mọ́?“Ẹ ní iyọ̀ ninu ara yín, nígbà náà ni alaafia yóo wà láàrin yín.”

Ka pipe ipin Maku 9