Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Maku 9:41-49 BIBELI MIMỌ (BM)

41. Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá fun yín ní omi mu nítorí tèmi, nítorí pé ẹ jẹ́ ti Kristi, mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé yóo rí èrè rẹ̀ gbà.

42. “Ẹnikẹ́ni tí ó bá mú ọ̀kan ninu àwọn kéékèèké wọnyi tí ó gbà mí gbọ́ kọsẹ̀, ó sàn fún un kí á so ọlọ ńlá mọ́ ọn lọ́rùn, kí á gbé e sọ sinu òkun.

43. Bí ọwọ́ rẹ bá mú ọ kọsẹ̀, gé e sọnù, ó sàn fún ọ kí o wọ inú ìyè pẹlu àléébù ara, jù pé kí o ní ọwọ́ mejeeji kí o wọ iná àjóòkú, [

44. níbi tí ìdin wọn kì í kú, tí iná ibẹ̀ kì í sì í kú.]

45. Bí ẹsẹ̀ rẹ bá mú ọ kọsẹ̀, gé e sọnù, ó sàn fún ọ kí o jẹ́ ẹlẹ́sẹ̀ kan kí o sì wọ inú ìyè jù pé kí o ní ẹsẹ̀ mejeeji kí á sì sọ ọ́ sinu iná, [

46. níbi tí ìdin wọn kì í kú, tí iná ibẹ̀ kì í sì í kú.]

47. Bí ojú rẹ bá mú ọ kọsẹ̀, yọ ọ́ sọnù, ó sàn fún ọ kí o wọ ìjọba Ọlọrun pẹlu ojú kan jù pé kí o ní ojú mejeeji kí a sì sọ ọ́ sinu iná,

48. níbi tí ìdin wọn kì í kú, tí iná ibẹ̀ kì í sì í kú.

49. “Iyọ̀ níí sọ ẹbọ di mímọ́, bẹ́ẹ̀ gan-an ni ó jẹ́ pé iná ni a óo fi sọ gbogbo eniyan di mímọ́.

Ka pipe ipin Maku 9