Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Maku 5:31-43 BIBELI MIMỌ (BM)

31. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wí fún un pé, “O rí i bí àwọn eniyan ti ń fún ọ lọ́tùn-ún lósì, o tún ń bèèrè pé ta ni fọwọ́ kàn ọ́?”

32. Ṣugbọn Jesu ń wò yíká láti rí ẹni tí ó fọwọ́ kan aṣọ rẹ̀.

33. Obinrin náà mọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ lára òun, ó bá yọ jáde. Ẹ̀rù bà á, ó ń gbọ̀n, ó bá wá kúnlẹ̀ níwájú Jesu, ó sọ gbogbo òtítọ́ ọ̀rọ̀ náà fún un.

34. Jesu wí fún un pé, “Arabinrin, igbagbọ rẹ ti mú ọ lára dá. Máa lọ ní alaafia, o kò ní gbúròó àìsàn náà mọ́.”

35. Kò tíì dákẹ́ ọ̀rọ̀ tí ń sọ, ni àwọn kan bá dé láti ilé olórí ilé ìpàdé tí Jesu ń bá lọ sílé, wọ́n ní, “Ọmọdebinrin rẹ ti kú, kí ni o tún ń yọ olùkọ́ni lẹ́nu sí?”

36. Ṣugbọn Jesu kò pé òun gbọ́ ohun tí wọn ń sọ, ó wí fún ọkunrin náà pé, “Má bẹ̀rù, ṣá ti gbàgbọ́.”

37. Kò jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tẹ̀lé òun àfi Peteru ati Jakọbu ati Johanu àbúrò Jakọbu.

38. Nígbà tí wọ́n dé ilé olórí ilé ìpàdé náà, Jesu rí bí gbogbo ilé ti dàrú, tí ẹkún ati ariwo ń sọ gèè.

39. Ó bá wọ inú ilé lọ, ó ní, “Kí ló dé tí ẹ fi ń kígbe, tí ẹ̀ ń sunkún bẹ́ẹ̀? Ọmọde náà kò kú; ó sùn ni.”

40. Wọ́n bá ń fi ṣe yẹ̀yẹ́, ó bá lé gbogbo wọn jáde. Ó wá mú baba ati ìyá ọmọ náà pẹlu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn tí ó wà pẹlu rẹ̀, ó wọ yàrá tí ọmọde náà wà lọ.

41. Ó bá fa ọmọde náà lọ́wọ́, ó wí fún un pé, “Talita kumi” ìtumọ̀ èyí tíí ṣe, “Ìwọ ọmọde yìí, mo wí fún ọ, dìde.”

42. Lẹsẹkẹsẹ ọmọdebinrin náà dìde, ó bá ń rìn, nítorí ọmọ ọdún mejila ni. Ìyàlẹ́nu ńlá ni ó jẹ́ fún gbogbo wọn.

43. Jesu wá kìlọ̀ fún wọn gan-an pé kí wọn má jẹ́ kí ẹnikẹ́ni mọ̀. Ó ní kí wọn wá oúnjẹ fún ọmọde náà kí ó jẹ.

Ka pipe ipin Maku 5