Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Maku 5:30-39 BIBELI MIMỌ (BM)

30. Lójú kan náà Jesu mọ̀ ninu ara rẹ̀ pé agbára ìwòsàn jáde lára òun. Ó bá yipada sí àwọn eniyan, ó bèèrè pé, “Ta ni fọwọ́ kàn mí láṣọ?”

31. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wí fún un pé, “O rí i bí àwọn eniyan ti ń fún ọ lọ́tùn-ún lósì, o tún ń bèèrè pé ta ni fọwọ́ kàn ọ́?”

32. Ṣugbọn Jesu ń wò yíká láti rí ẹni tí ó fọwọ́ kan aṣọ rẹ̀.

33. Obinrin náà mọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ lára òun, ó bá yọ jáde. Ẹ̀rù bà á, ó ń gbọ̀n, ó bá wá kúnlẹ̀ níwájú Jesu, ó sọ gbogbo òtítọ́ ọ̀rọ̀ náà fún un.

34. Jesu wí fún un pé, “Arabinrin, igbagbọ rẹ ti mú ọ lára dá. Máa lọ ní alaafia, o kò ní gbúròó àìsàn náà mọ́.”

35. Kò tíì dákẹ́ ọ̀rọ̀ tí ń sọ, ni àwọn kan bá dé láti ilé olórí ilé ìpàdé tí Jesu ń bá lọ sílé, wọ́n ní, “Ọmọdebinrin rẹ ti kú, kí ni o tún ń yọ olùkọ́ni lẹ́nu sí?”

36. Ṣugbọn Jesu kò pé òun gbọ́ ohun tí wọn ń sọ, ó wí fún ọkunrin náà pé, “Má bẹ̀rù, ṣá ti gbàgbọ́.”

37. Kò jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tẹ̀lé òun àfi Peteru ati Jakọbu ati Johanu àbúrò Jakọbu.

38. Nígbà tí wọ́n dé ilé olórí ilé ìpàdé náà, Jesu rí bí gbogbo ilé ti dàrú, tí ẹkún ati ariwo ń sọ gèè.

39. Ó bá wọ inú ilé lọ, ó ní, “Kí ló dé tí ẹ fi ń kígbe, tí ẹ̀ ń sunkún bẹ́ẹ̀? Ọmọde náà kò kú; ó sùn ni.”

Ka pipe ipin Maku 5