Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Maku 5:12-23 BIBELI MIMỌ (BM)

12. Àwọn ẹ̀mí èṣù náà bẹ̀ ẹ́ pé kí ó rán wọn sí ààrin ẹlẹ́dẹ̀ náà, kí wọ́n lè wọ inú wọn.

13. Ó bá gbà bẹ́ẹ̀ fún wọn. Àwọn ẹ̀mí èṣù náà jáde lọ, wọ́n wọ inú àwọn ẹlẹ́dẹ̀ náà. Agbo ẹlẹ́dẹ̀ náà bá tú pẹ̀ẹ́, wọ́n sáré láti gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè lọ sí òkun, wọ́n bá rì sinu òkun. Wọ́n tó bí ẹgbaa (2,000).

14. Àwọn olùtọ́jú wọn bá sálọ sí àwọn ìlú ati àwọn abúlé tí ó wà yíká láti ròyìn ohun tí ó ṣẹlẹ̀. Àwọn eniyan bá wá fi ojú ara wọn rí ohun tí ó ṣẹlẹ̀.

15. Nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ Jesu, wọ́n rí ọkunrin náà tí ó ti jẹ́ wèrè rí, tí ó ti ní ẹgbaagbeje ẹ̀mí èṣù, ó jókòó, ó wọ aṣọ, iyè rẹ̀ sì ti bọ̀ sípò. Ẹ̀rù ba àwọn eniyan tí ó rí i.

16. Àwọn tí ọ̀rọ̀ náà ṣe ojú wọn ròyìn ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí ọkunrin náà ati àwọn ẹlẹ́dẹ̀.

17. Àwọn eniyan bá bẹ̀rẹ̀ sí bẹ Jesu pé kí ó kúrò ní agbègbè wọn.

18. Bí ó ti ń wọ ọkọ̀ ojú omi pada, ọkunrin tí ó ti jẹ́ wèrè rí yìí bẹ̀ ẹ́ pé kí ó jẹ́ kí òun máa bá a lọ.

19. Ṣugbọn Jesu kọ̀ fún un, ó sọ fún un pé, “Lọ sí ilé rẹ, sọ́dọ̀ àwọn ẹbí rẹ, kí o sọ ohun tí Oluwa ti ṣe fún ọ ati bí ó ti ṣàánú rẹ.”

20. Ọkunrin náà lọ, ó bẹ̀rẹ̀ sí ròyìn ohun tí Jesu ṣe fún un ní agbègbè Ìlú Mẹ́wàá, ẹnu sì ya gbogbo eniyan tí ó gbọ́.

21. Nígbà tí Jesu tún rékọjá lọ sí òdìkejì òkun, ọpọlọpọ eniyan wọ́ jọ pọ̀ sọ́dọ̀ rẹ̀ lẹ́bàá òkun.

22. Ọkunrin kan wà tí ń jẹ́ Jairu, aṣaaju kan ni ní ilé ìpàdé ibẹ̀. Nígbà tí ó rí Jesu, ó dojúbolẹ̀ níwájú rẹ̀,

23. ó bẹ̀rẹ̀ sí bẹ̀ ẹ́. Ó ní, “Ọmọdebinrin mi ń kú lọ, wá gbé ọwọ́ lé e, kí ó lè yè.”

Ka pipe ipin Maku 5