10. Lẹ́yìn èyí, Jesu fúnrarẹ̀ rán wọn lọ jákèjádò ayé láti kéde ìyìn rere ìgbàlà ayérayé, ìyìn rere tí ó ní ọ̀wọ̀, tí kò sì lè díbàjẹ́ lae.][
9. Nígbà tí Jesu jí dìde ní òwúrọ̀ ọjọ́ kinni ọ̀sẹ̀, ó kọ́ fara han Maria Magidaleni, tí Jesu lé ẹ̀mí èṣù meje kúrò ninu rẹ̀ nígbà kan.
10. Ó lọ sọ fún àwọn tí ó ti ń bá Jesu gbé níbi tí wọn ti ń ṣọ̀fọ̀, tí wọn ń sunkún.
11. Nígbà tí wọ́n gbọ́ pé Jesu wà láàyè ati pé Maria ti rí i, wọn kò gbàgbọ́.
12. Lẹ́yìn náà, ó fara han àwọn meji kan ninu wọn ní ọ̀nà mìíràn, bí wọ́n ti ń rìn lọ sí ìgbèríko kan.
13. Wọ́n bá pada lọ ròyìn fún àwọn ìyókù. Sibẹ wọn kò gbàgbọ́.
14. Lẹ́yìn náà ó fara han àwọn mọkanla bí wọ́n ti ń jẹun. Ó bá wọn wí fún aigbagbọ ati ọkàn líle wọn, nítorí wọn kò gba àwọn tí wọ́n rí i, tí wọ́n sọ pé ó ti jinde gbọ́.
15. Ó bá sọ fún wọn pé, “Ẹ lọ sí gbogbo ayé, kí ẹ máa waasu ìyìn rere fún gbogbo ẹ̀dá.
16. Ẹni tí ó bá gbàgbọ́, tí ó bá ṣe ìrìbọmi, yóo ní ìgbàlà. Ẹni tí kò bá gbàgbọ́ yóo gba ìdálẹ́bi.
17. Àwọn àmì tí yóo máa bá àwọn tí ó gbàgbọ́ lọ nìwọ̀nyí; wọn yóo máa lé ẹ̀mí burúkú jáde ní orúkọ mi; wọn yóo máa fi àwọn èdè titun sọ̀rọ̀;