Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Maku 15:29-47 BIBELI MIMỌ (BM)

29. Àwọn tí ń kọjá lọ ń sọ ìsọkúsọ sí i, wọ́n ń já apá mọ́nú, wọ́n ń wí pé, “Kò tán an! Ìwọ tí yóo wó Tẹmpili, tí yóo tún kọ́ ọ ní ọjọ́ mẹta,

30. gba ara rẹ là, sọ̀kalẹ̀ láti orí agbelebu.”

31. Bákan náà ni àwọn olórí alufaa pẹlu àwọn amòfin ń fi ṣe ẹlẹ́yà láàrin ara wọn, wọ́n ń wí pé, “Àwọn ẹlòmíràn ni ó le gbà là, kò lè gba ara rẹ̀ là.

32. Kí Kristi ọba Israẹli sọ̀kalẹ̀ láti orí agbelebu nisinsinyii, kí á rí i, kí á lè gbàgbọ́.”Àwọn tí a kàn mọ́ agbelebu pẹlu rẹ̀ náà ń bu ẹ̀tẹ́ lù ú.

33. Láti agogo mejila ọ̀sán ni òkùnkùn ti bo gbogbo ilẹ̀, títí di agogo mẹta ọ̀sán.

34. Nígbà tí ó di agogo mẹta ọ̀sán, Jesu kígbe tòò, ó ní, “Eloi, Eloi, lema sabakitani?” Ìtumọ̀ èyí ni, “Ọlọrun mi, Ọlọrun mi, kí ló dé tí o fi kọ̀ mí sílẹ̀?”

35. Nígbà tí àwọn kan ninu àwọn tí ó dúró níbẹ̀ gbọ́, wọ́n ń wí pé, “Ẹ gbọ́! Ó ń pe Elija!”

36. Ẹnìkan bá sáré, ó ti kinní kan bíi kànìnkànìn bọ inú ọtí kíkan, ó fi sí orí ọ̀pá láti fún un mu, ó ń wí pé, “Ẹ jẹ́ kí á máa wò ó bí Elija yóo wá gbé e sọ̀kalẹ̀!”

37. Ṣugbọn Jesu kígbe tòò, ó mí kanlẹ̀ ó bá dákẹ́.

38. Aṣọ ìkélé tí ó wà ninu Tẹmpili bá ya sí meji láti òkè dé ilẹ̀.

39. Nígbà tí ọ̀gágun tí ó dúró lọ́kàn-ánkán rẹ̀ rí bí ó ti dákẹ́ lẹ́yìn tí ó ti kígbe, ó ní, “Dájúdájú, ọmọ Ọlọrun ni ọkunrin yìí.”

40. Àwọn obinrin kan wà ní òkèèrè tí wọn ń wo gbogbo ohun tí ń ṣẹlẹ̀. Ninu wọn ni Maria Magidaleni wà, ati Maria ìyá Jakọbu kékeré ati ìyá Josẹfu, ati Salomi.

41. Àwọn wọnyi ti ń tẹ̀lé e láti ìgbà tí ó ti wà ní Galili, tí wọn ń ṣe iranṣẹ fún un. Ọpọlọpọ àwọn obinrin mìíràn wà níbẹ̀ tí wọ́n bá a gòkè wá sí Jerusalẹmu.

42-43. Ọjọ́ náà jẹ́ ọjọ́ ìpalẹ̀mọ́ tíí ṣe ọ̀sẹ̀ ku ọ̀la. Nígbà tí ó di ìrọ̀lẹ́, Josẹfu ará Arimatia, ọlọ́lá kan ninu àwọn ìgbìmọ̀, wá. (Ó ń retí àkókò ìjọba Ọlọrun), ó bá fi ìgboyà tọ Pilatu lọ láti bèèrè òkú Jesu.

44. Ṣugbọn ẹnu ya Pilatu pé Jesu ti yára kú! Ó pe ọ̀gágun, ó bèèrè bí Jesu ti kú tipẹ́.

45. Nígbà tí ó gbọ́ ìròyìn ọ̀gágun náà, ó yọ̀ǹda òkú Jesu fún Josẹfu.

46. Josẹfu bá ra aṣọ funfun kan, ó sọ òkú Jesu kalẹ̀, ó fi aṣọ náà wé e, ó tẹ́ ẹ sí ibojì tí wọ́n gbẹ́ sí inú àpáta, lẹ́yìn náà ó yí òkúta dí ẹnu ibojì náà.

47. Maria Magidaleni ati Maria ìyá Josẹfu ń wo ibi tí wọ́n tẹ́ ẹ sí.

Ka pipe ipin Maku 15