Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Maku 14:56-65 BIBELI MIMỌ (BM)

56. Nítorí ọpọlọpọ ní ń jẹ́rìí èké sí i, ṣugbọn ẹ̀rí wọn kò bá ara wọn mu.

57. Àwọn kan wá dìde, wọ́n ń jẹ́rìí èké sí i pé,

58. “A gbọ́ nígbà tí ó ń wí pé, ‘Èmi yóo wó Tẹmpili tí eniyan kọ́ yìí, láàrin ọjọ́ mẹta, èmi óo gbé òmíràn dìde tí eniyan kò kọ́.’ ”

59. Sibẹ ẹ̀rí wọn kò bá ara wọn mu.

60. Nígbà náà ni Olórí Alufaa dìde láàrin wọn, ó bi Jesu pé, “Ìwọ kò fèsì rárá?”

61. Ṣugbọn ó sá dákẹ́ ni, kò fèsì kankan.Olórí Alufaa tún bi í pé, “Ìwọ ni Kristi náà, Ọmọ Olùbùkún?”

62. Jesu dáhùn pé, “Èmi ni. Ẹ óo rí Ọmọ-Eniyan tí ó jókòó lórí ìtẹ́ pẹlu agbára Ọlọrun, tí ìkùukùu yóo sì máa gbé e bọ̀ wá.”

63. Olórí Alufaa bá fa ẹ̀wù rẹ̀ ya, ó ní, “Ẹlẹ́rìí wo ni a tún ń wá?

64. Ẹ ti gbọ́ tí ó sọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọrun! Kí ni ẹ wí?”Gbogbo wọn bá dá a lẹ́bi, wọ́n ní ikú ni ó tọ́ sí i.

65. Àwọn kan bẹ̀rẹ̀ sí tutọ́ sí i lára. Wọ́n fi aṣọ bò ó lójú, wọ́n wá ń sọ ọ́ ní ẹ̀ṣẹ́. Wọ́n sọ fún un pé, “Sọ ẹni tí ó lù ọ́ fún wa, wolii!” Àwọn iranṣẹ wá ń gbá a létí bí wọn ti ń mú un lọ sí àtìmọ́lé.

Ka pipe ipin Maku 14