Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Maku 14:32-41 BIBELI MIMỌ (BM)

32. Wọ́n dé ibìkan tí wọn ń pè ní Gẹtisemani. Ó wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ẹ jókòó níhìn-ín nígbà tí mo bá lọ gbadura.”

33. Ó wá mú Peteru, Jakọbu ati Johanu pẹlu rẹ̀. Àyà bẹ̀rẹ̀ sí pá a, ó bẹ̀rẹ̀ sí dààmú.

34. Ó wí fún wọn pé, “Ọkàn mi bàjẹ́ tóbẹ́ẹ̀ tí mo fẹ́rẹ̀ lè kú. Ẹ dúró níhìn-ín kí ẹ máa ṣọ́nà.”

35. Ó bá lọ sí iwájú díẹ̀, ó dojúbolẹ̀, ó ń gbadura pé bí ó bá ṣeéṣe kí àkókò yìí kọjá lórí òun.

36. Ó ní, “Baba, Baba, ohun gbogbo ṣeéṣe fún ọ. Mú kí ife kíkorò yìí kọjá kúrò lórí mi. Ṣugbọn ìfẹ́ tìrẹ ni kí o ṣe, kì í ṣe ìfẹ́ tèmi.”

37. Ó pada lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ mẹta, ó rí i pé wọ́n ti sùn lọ! Ó wí fún Peteru pé, “Simoni, ò ń sùn ni? O kò lè ṣọ́nà fún wakati kan péré?

38. Gbogbo yín, ẹ máa ṣọ́nà, kí ẹ tún máa gbadura, kí ẹ má baà bọ́ sinu ìdánwò. Ẹ̀mí fẹ́ ṣe é, ṣugbọn ara kò lágbára.”

39. Ó tún lọ gbadura, ó sọ àwọn ọ̀rọ̀ kan náà bíi ti àkọ́kọ́.

40. Ó tún wá, ó rí i pé wọ́n tún ń sùn, nítorí pé oorun ń kùn wọ́n pupọ. Wọn kò wá mọ ìdáhùn tí wọn ì bá fi fún un mọ́.

41. Ó pada wá ní ẹẹkẹta, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ ṣì wà níbi tí ẹ̀ ń sùn, tí ẹ̀ ń gbádùn ìsinmi yín? Àbùṣe bùṣe! Àkókò náà tó. Wọn yóo fi Ọmọ-Eniyan lé àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ lọ́wọ́.

Ka pipe ipin Maku 14