Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Maku 13:33-37 BIBELI MIMỌ (BM)

33. Ẹ ṣọ́ra, ẹ máa fojú sọ́nà nítorí ẹ kò mọ wakati náà.

34. Ó dàbí kí ọkunrin kan máa lọ sí ìdálẹ̀, kí ó fi ilé rẹ̀ sílẹ̀, kí ó fi àṣẹ fún àwọn iranṣẹ rẹ̀, kí ó fi iṣẹ́ ẹnìkọ̀ọ̀kan fún un, kí ó wá pàṣẹ fún olùṣọ́nà pé kí ó ṣọ́nà.

35. Bẹ́ẹ̀ gan-an ni kí ẹ máa ṣọ́nà nítorí ẹ kò mọ ìgbà tí baálé ilé náà yóo dé: bí ní ìrọ̀lẹ́ ni, tabi ní ọ̀gànjọ́, tabi ní àkùkọ ìdájí, tabi ní àfẹ̀mọ́jú.

36. Bí ó bá dé lójijì, kí ó má baà ba yín lójú oorun.

37. Ohun tí mò ń wí fun yín ni mò ń wí fún gbogbo eniyan: ẹ máa ṣọ́nà.”

Ka pipe ipin Maku 13