Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Maku 11:23-33 BIBELI MIMỌ (BM)

23. mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, bí ẹnikẹ́ni bá wí fún òkè yìí pé, ‘ṣídìí kúrò níbi tí o wà, kí o bọ́ sí inú òkun,’ tí kò bá ṣiyèméjì, ṣugbọn tí ó gbàgbọ́ pé, ohun tí òun wí yóo rí bẹ́ẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni yóo rí fún un.

24. Nítorí èyí, mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé, ohun gbogbo tí ẹ bá bèèrè ninu adura, ẹ gbàgbọ́ pé ẹ ti rí i gbà, bẹ́ẹ̀ ni yóo rí fun yín.

25. Nígbà tí ẹ bá dìde dúró láti gbadura, ẹ dáríjì ẹnikẹ́ni tí ẹ bá ní ohunkohun ninu sí, kí Baba yín ọ̀run lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ yín jì yín. [

26. Bí ẹ kò bá dárí ji eniyan, Baba yín ọ̀run kò ní dárí ẹ̀ṣẹ̀ yín jì yín.”]

27. Wọ́n tún wá sí Jerusalẹmu. Bí Jesu ti ń rìn kiri ninu Tẹmpili, àwọn olórí alufaa, ati àwọn amòfin, ati àwọn àgbà wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀.

28. Wọ́n ń bi í pé, “Irú àṣẹ wo ni o fi ń ṣe nǹkan wọnyi? Ta ni ó fún ọ ní àṣẹ tí o fi ń ṣe wọ́n?”

29. Jesu dá wọn lóhùn, ó ní, “N óo bi yín léèrè ọ̀rọ̀ kan, ẹ dá mi lóhùn, èmi náà óo wá sọ irú àṣẹ tí mo fi ń ṣe nǹkan wọnyi.

30. Ìrìbọmi tí Johanu ń ṣe, láti ọ̀run ni ó ti gba àṣẹ ni, tabi láti ọwọ́ eniyan? Ẹ dá mi lóhùn.”

31. Nígbà náà ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí bá ara wọn jiyàn pé, “Bí a bá wí pé, ‘Láti ọ̀run ni,’ yóo sọ pé, ‘Kí ló dé tí ẹ kò fi gbà á gbọ́?’

32. Àbí kí a wí pé, ‘Láti ọwọ́ eniyan ni?’ ” Wọ́n bẹ̀rù àwọn eniyan nítorí gbogbo eniyan ni ó gbà pé wolii tòótọ́ ni Johanu.

33. Wọ́n bá dá Jesu lóhùn pé, “Àwa kò mọ̀.”Nígbà náà ni Jesu sọ fún wọn pé, “Èmi náà kò ní sọ irú àṣẹ tí mo fi ń ṣe àwọn nǹkan wọnyi fun yín.”

Ka pipe ipin Maku 11