Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Maku 10:41-52 BIBELI MIMỌ (BM)

41. Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mẹ́wàá yòókù gbọ́, inú bẹ̀rẹ̀ sí bí wọn sí Jakọbu ati Johanu.

42. Ni Jesu bá pè wọ́n, ó wí fún wọn pé, “Ẹ mọ̀ pé àwọn aláṣẹ láàrin àwọn alaigbagbọ a máa jẹ ọlá lórí wọn, àwọn eniyan ńláńlá ninu wọn a sì máa lo agbára lórí wọn,

43. ṣugbọn tiyín kò gbọdọ̀ rí bẹ́ẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ jẹ́ pataki láàrin yín níláti jẹ́ iranṣẹ yín;

44. ẹnikẹ́ni tí ó bá sì fẹ́ jẹ́ aṣaaju ninu yín níláti máa ṣe ẹrú gbogbo yín.

45. Nítorí Ọmọ-Eniyan pàápàá kò wá pé kí eniyan ṣe iranṣẹ fún un, ó wá láti ṣe iranṣẹ ni, ati láti fi ẹ̀mí rẹ̀ ṣe ìràpadà fún ọpọlọpọ eniyan.”

46. Wọn dé Jẹriko. Bí Jesu pẹlu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ati ogunlọ́gọ̀ eniyan ti ń jáde kúrò ní Jẹriko, Batimiu afọ́jú, ọmọ Timiu, jókòó lẹ́bàá ọ̀nà, ó ń ṣagbe.

47. Nígbà tí ó gbọ́ pé Jesu ará Nasarẹti ni ó dé, ó bẹ̀rẹ̀ sí kígbe pé, “Jesu! Ọmọ Dafidi! Ṣàánú mi!”

48. Ọpọlọpọ eniyan ń bá a wí pé kí ó panu mọ́. Ṣugbọn sibẹ ó túbọ̀ ń kígbe pé, “Ọmọ Dafidi! Ṣàánú mi.”

49. Jesu bá dúró, ó ní, “Ẹ pè é wá.”Wọ́n wá wí fún afọ́jú náà pé, “Ṣe ara gírí, dìde, ó ń pè ọ́.”

50. Bẹ́ẹ̀ ni ọkunrin náà bọ́ aṣọ rẹ̀ sọ sí apá kan, ó fò sókè, ó bá lọ sí ọ̀dọ̀ Jesu.

51. Jesu bi í pé, “Kí ni o fẹ́ kí n ṣe fún ọ?”Afọ́jú náà dáhùn pé, “Olùkọ́ni, mo fẹ́ tún ríran ni.”

52. Jesu bá wí fún un pé, “Máa lọ, igbagbọ rẹ ti mú ọ lára dá.”Lójú kan náà, afọ́jú náà bá ríran, ó bá ń bá Jesu lọ ní ọ̀nà.

Ka pipe ipin Maku 10