Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Maku 10:36-52 BIBELI MIMỌ (BM)

36. Jesu bi wọ́n pé, “Kí ni ẹ fẹ́ kí n ṣe fun yín?”

37. Wọ́n ní, “Gbà fún wa pé, nígbà tí ó bá di ìgbà ìgúnwà rẹ, kí ọ̀kan ninu wa jókòó ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀tún rẹ, kí ẹnìkejì jókòó ní ẹ̀gbẹ́ òsì rẹ.”

38. Ṣugbọn Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ẹ̀yin kò mọ ohun tí ẹ̀ ń bèèrè. Ṣé ẹ lè mu ninu ife ìrora tí èmi yóo mu, tabi kí ojú yín rí irú ìṣòro tí ojú mi yóo rí?”

39. Wọ́n wí fún un pé, “Àwa lè ṣe é.”Ṣugbọn Jesu wí fún wọn pé, “Ninu irú ife ìrora tí n óo mu ẹ̀yin náà yóo mu, irú ìṣòro tí ojú mi yóo rí, tiyín náà yóo sì rí i.

40. Ṣugbọn ní ti jíjókòó ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀tún ati ẹ̀gbẹ́ òsì mi, kì í ṣe tèmi láti fún ẹnikẹ́ni, ipò wọnyi wà fún àwọn tí Ọlọrun ti pèsè wọn sílẹ̀ fún.”

41. Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mẹ́wàá yòókù gbọ́, inú bẹ̀rẹ̀ sí bí wọn sí Jakọbu ati Johanu.

42. Ni Jesu bá pè wọ́n, ó wí fún wọn pé, “Ẹ mọ̀ pé àwọn aláṣẹ láàrin àwọn alaigbagbọ a máa jẹ ọlá lórí wọn, àwọn eniyan ńláńlá ninu wọn a sì máa lo agbára lórí wọn,

43. ṣugbọn tiyín kò gbọdọ̀ rí bẹ́ẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ jẹ́ pataki láàrin yín níláti jẹ́ iranṣẹ yín;

44. ẹnikẹ́ni tí ó bá sì fẹ́ jẹ́ aṣaaju ninu yín níláti máa ṣe ẹrú gbogbo yín.

45. Nítorí Ọmọ-Eniyan pàápàá kò wá pé kí eniyan ṣe iranṣẹ fún un, ó wá láti ṣe iranṣẹ ni, ati láti fi ẹ̀mí rẹ̀ ṣe ìràpadà fún ọpọlọpọ eniyan.”

46. Wọn dé Jẹriko. Bí Jesu pẹlu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ati ogunlọ́gọ̀ eniyan ti ń jáde kúrò ní Jẹriko, Batimiu afọ́jú, ọmọ Timiu, jókòó lẹ́bàá ọ̀nà, ó ń ṣagbe.

47. Nígbà tí ó gbọ́ pé Jesu ará Nasarẹti ni ó dé, ó bẹ̀rẹ̀ sí kígbe pé, “Jesu! Ọmọ Dafidi! Ṣàánú mi!”

48. Ọpọlọpọ eniyan ń bá a wí pé kí ó panu mọ́. Ṣugbọn sibẹ ó túbọ̀ ń kígbe pé, “Ọmọ Dafidi! Ṣàánú mi.”

49. Jesu bá dúró, ó ní, “Ẹ pè é wá.”Wọ́n wá wí fún afọ́jú náà pé, “Ṣe ara gírí, dìde, ó ń pè ọ́.”

50. Bẹ́ẹ̀ ni ọkunrin náà bọ́ aṣọ rẹ̀ sọ sí apá kan, ó fò sókè, ó bá lọ sí ọ̀dọ̀ Jesu.

51. Jesu bi í pé, “Kí ni o fẹ́ kí n ṣe fún ọ?”Afọ́jú náà dáhùn pé, “Olùkọ́ni, mo fẹ́ tún ríran ni.”

52. Jesu bá wí fún un pé, “Máa lọ, igbagbọ rẹ ti mú ọ lára dá.”Lójú kan náà, afọ́jú náà bá ríran, ó bá ń bá Jesu lọ ní ọ̀nà.

Ka pipe ipin Maku 10