Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Luku 8:50-56 BIBELI MIMỌ (BM)

50. Ṣugbọn nígbà tí Jesu gbọ́, ó dá a lóhùn pé, “Má bẹ̀rù, ṣá gbàgbọ́, ara ọmọ rẹ yóo dá.”

51. Nígbà tí Jesu dé ilé, kò jẹ́ kí ẹnikẹ́ni wọlé àfi Peteru, Johanu ati Jakọbu, baba ati ìyá ọmọ náà.

52. Gbogbo àwọn eniyan ń sunkún, wọ́n ń dárò nítorí ọmọ náà. Ṣugbọn Jesu ní, “Ẹ má sunkún mọ́, nítorí ọmọ náà kò kú, ó ń sùn ni.”

53. Ńṣe ni wọ́n ń fi Jesu rẹ́rìn-ín ẹlẹ́yà, nítorí wọ́n mọ̀ pé ọmọ náà ti kú.

54. Jesu fa ọmọ náà lọ́wọ́, ó sọ fún un pé, “Ọmọ, dìde.”

55. Ẹ̀mí rẹ̀ bá pada sinu rẹ̀, ni ó bá dìde lẹsẹkẹsẹ. Jesu bá sọ fún wọn pé kí wọn fún un ní oúnjẹ.

56. Ẹnu ya àwọn òbí ọmọ náà. Ṣugbọn ó kìlọ̀ fún wọn pé kí wọn má ṣe sọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún ẹnikẹ́ni.

Ka pipe ipin Luku 8