Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Luku 5:21-25 BIBELI MIMỌ (BM)

21. Àwọn amòfin ati àwọn Farisi bẹ̀rẹ̀ sí bá ara wọn sọ pé, “Ta ni eléyìí tí ó ń sọ̀rọ̀ àfojúdi sí Ọlọrun báyìí? Ta ni lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ ji eniyan lẹ́yìn Ọlọrun nìkan ṣoṣo?”

22. Jesu ti mọ ohun tí wọ́n ń bá ara wọn sọ, ó bá dá wọn lóhùn pé, “Kí ló dé tí ẹ fi ń ro irú èrò báyìí ní ọkàn yín?

23. Èwo ni ó rọrùn jù, láti sọ pé, ‘A dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́ ni,’ tabi láti sọ pé, ‘Dìde kí o máa rìn’?

24. Ṣugbọn kí ẹ lè mọ̀ pé Ọmọ-Eniyan ní àṣẹ ní ayé láti dárí ẹ̀ṣẹ̀ ji eniyan ni,” ó bá sọ fún arọ náà pé, “Mo sọ fún ọ, dìde, gbé ibùsùn rẹ, kí o máa lọ sí ilé rẹ.”

25. Lẹsẹkẹsẹ ó dìde lójú gbogbo wọn, ó gbé ibùsùn rẹ̀, ó lọ sí ilé rẹ̀, ó ń yin Ọlọrun lógo.

Ka pipe ipin Luku 5