Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Luku 22:57-67 BIBELI MIMỌ (BM)

57. Ṣugbọn Peteru sẹ́, ó ní, “N kò tilẹ̀ mọ ọkunrin yìí!”

58. Nígbà tí ó ṣe díẹ̀, ẹlòmíràn tún rí i, ó ní, “Ìwọ náà wà láàrin wọn.”Ṣugbọn Peteru ní, “Ọkunrin yìí, n kò sí níbẹ̀!”

59. Nígbà tí ó tó bíi wakati kan, ọkunrin kan tún sọ pẹlu ìdánilójú pé, “Láìsí àní-àní ọkunrin yìí wà pẹlu Jesu, nítorí ará Galili ni.”

60. Ṣugbọn Peteru dáhùn pé, “Ọkunrin yìí, n kò mọ ohun tí ò ń sọ!”Lẹsẹkẹsẹ, ó fẹ́rẹ̀ ma tíì dákẹ́ ọ̀rọ̀ tí ó ń sọ, àkùkọ bá kọ.

61. Oluwa yipada, ó wo Peteru, Peteru wá ranti ọ̀rọ̀ Oluwa nígbà tí ó sọ fún un pé, “Kí àkùkọ tó kọ lálẹ́ yìí, ìwọ yóo sẹ́ mi lẹẹmẹta.”

62. Peteru bá jáde lọ, ó bú sẹ́kún, ó bẹ̀rẹ̀ sí hu gan-an.

63. Àwọn ọkunrin tí wọn ń ṣọ́ Jesu ń fi í ṣe ẹlẹ́yà, wọ́n sì ń lù ú.

64. Wọ́n daṣọ bò ó lójú, wọ́n wá ń bi í pé, “Sọ ẹni tí ó lù ọ́?”

65. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń sọ oríṣìíríṣìí ìsọkúsọ sí i.

66. Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, àwọn àgbààgbà ati àwọn olórí alufaa ati àwọn amòfin péjọ, wọ́n fa Jesu lọ siwaju ìgbìmọ̀ wọn.

67. Wọ́n bi í pé, “Sọ fún wa, ṣé ìwọ ni Mesaya náà?”Ó dá wọn lóhùn pé, “Bí mo bá sọ fun yín, ẹ kò ní gbàgbọ́.

Ka pipe ipin Luku 22