Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Luku 20:9-19 BIBELI MIMỌ (BM)

9. Ó wá pa òwe yìí fún àwọn eniyan. Ó ní, “Ọkunrin kan gbin àjàrà sinu ọgbà kan, ó gba àwọn alágbàro sibẹ, ó bá lọ sí ìrìn àjò. Ó pẹ́ níbi tí ó lọ.

10. Nígbà tí ó yá, ó rán ẹrú rẹ̀ kan sí àwọn alágbàro náà. Ṣugbọn àwọn alágbàro yìí lù ú, wọ́n bá dá a pada ní ọwọ́ òfo.

11. Ọkunrin yìí tún rán ẹrú mìíràn. Àwọn alágbàro yìí tún lù ú, wọ́n fi àbùkù kàn án, wọ́n bá tún dá òun náà pada ní ọwọ́ òfo.

12. Ọkunrin yìí tún rán ẹnìkẹta. Wọ́n tilẹ̀ ṣe òun léṣe ni, ní tirẹ̀, wọ́n bá lé e jáde.

13. Ẹni tí ó ni ọgbà yìí wá rò ninu ara rẹ̀ pé, ‘Kí ni n óo ṣe o? N óo rán àyànfẹ́ ọmọ mi, bóyá wọn yóo bọlá fún un.’

14. Ṣugbọn nígbà tí àwọn alágbàro yìí rí i, wọ́n bà ara wọn sọ pé, ‘Àrólé rẹ̀ nìyí. Ẹ jẹ́ kí á pa á, kí ogún rẹ̀ lè di tiwa.’

15. Ni wọ́n bá mú un jáde kúrò ninu ọgbà náà, wọ́n bá pa á.“Kí ni ẹni tí ó ni ọgbà náà yóo wá ṣe?

16. Yóo pa àwọn alágbàro wọnyi, yóo sì gbé ọgbà rẹ̀ fún àwọn mìíràn láti tọ́jú.”Nígbà tí wọ́n gbọ́, wọ́n ní “Ọlọrun má jẹ́!”

17. Jesu bá wò wọ́n lójú, ó ní, “Ǹjẹ́ kí ni ìtumọ̀ àkọsílẹ̀ yìí,‘Òkúta tí àwọn ọ̀mọ̀lé kọ̀ sílẹ̀,òun ni ó di òkúta pataki ní igun ilé.’

18. Bí ẹnikẹ́ni bá ṣubú lu òkúta yìí, olúwarẹ̀ yóo fọ́ yángá-yángá, bí òkúta yìí bá sì bọ́ lu ẹnikẹ́ni, rírẹ́ ni yóo rẹ́ olúwarẹ̀ pẹ́tẹ́pẹ́tẹ́.”

19. Àwọn akọ̀wé ati àwọn olórí alufaa gbèrò láti mú un ní wakati náà, nítorí wọ́n mọ̀ pé àwọn ni ó pa òwe yìí mọ́; ṣugbọn wọ́n bẹ̀rù àwọn eniyan.

Ka pipe ipin Luku 20