Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Luku 20:36-47 BIBELI MIMỌ (BM)

36. Nítorí wọn kò lè kú mọ́, nítorí bákan náà ni wọ́n rí pẹlu àwọn angẹli. Ọmọ Ọlọrun ni wọ́n, nítorí pé wọ́n jẹ́ ọmọ ajinde.

37. Ó dájú pé a jí àwọn òkú dìde nítorí ohun tí Mose kọ ninu ìtàn ìgbẹ́ tí ń jóná, nígbà tí ó sọ pé, ‘Oluwa Ọlọrun Abrahamu, Ọlọrun Isaaki, ati Ọlọrun ti Jakọbu.’

38. Ọlọrun kì í ṣe Ọlọrun àwọn òkú, ti àwọn alààyè ni; nítorí pé gbogbo wọn ni ó wà láàyè fún Ọlọrun.”

39. Àwọn kan ninu àwọn amòfin dá a lóhùn pé, “Olùkọ́ni, o wí ire!”

40. Láti ìgbà náà kò tún sí ẹni tí ó láyà láti bi í ní nǹkankan mọ́.

41. Jesu bi wọ́n léèrè pé, “Báwo ni wọ́n ṣe ń pe Mesaya ní ọmọ Dafidi?

42. Nítorí Dafidi sọ ninu ìwé Orin Dafidi pé,‘Oluwa wí fún oluwa mi pé:Jókòó lọ́wọ́ ọ̀tún mi

43. títí n óo fi sọ àwọn ọ̀tá rẹ di àpótí ìtìsẹ̀ rẹ.’

44. Nígbà tí Dafidi pè é ní Oluwa, báwo ni ó ti ṣe tún jẹ́ ọmọ rẹ̀?”

45. Ní etí gbogbo àwọn eniyan, Jesu sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé,

46. “Ẹ ṣọ́ra lọ́dọ̀ àwọn amòfin tí wọ́n fẹ́ máa wọ agbádá ńlá. Wọ́n tún gbádùn kí eniyan máa kí wọn ní ààrin ọjà. Wọ́n fẹ́ràn láti jókòó níwájú ninu ilé ìpàdé ati láti jókòó ní ipò ọlá níbi àsè.

47. Wọn a máa jẹ ilé àwọn opó run. Wọ́n a máa gba adura gígùn láti ṣe àṣehàn. Wọn yóo gba ìdájọ́ líle.”

Ka pipe ipin Luku 20