Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Luku 20:34-40 BIBELI MIMỌ (BM)

34. Jesu dá wọn lóhùn pé, “Àwọn eniyan ayé yìí ni wọ́n ń gbeyawo, tí wọn ń fi ọmọ fọ́kọ.

35. Ṣugbọn àwọn tí a kà yẹ fún ayé tí ó ń bọ̀, nígbà tí àwọn òkú bá jinde, kò ní máa gbeyawo, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní máa fọmọ fọ́kọ.

36. Nítorí wọn kò lè kú mọ́, nítorí bákan náà ni wọ́n rí pẹlu àwọn angẹli. Ọmọ Ọlọrun ni wọ́n, nítorí pé wọ́n jẹ́ ọmọ ajinde.

37. Ó dájú pé a jí àwọn òkú dìde nítorí ohun tí Mose kọ ninu ìtàn ìgbẹ́ tí ń jóná, nígbà tí ó sọ pé, ‘Oluwa Ọlọrun Abrahamu, Ọlọrun Isaaki, ati Ọlọrun ti Jakọbu.’

38. Ọlọrun kì í ṣe Ọlọrun àwọn òkú, ti àwọn alààyè ni; nítorí pé gbogbo wọn ni ó wà láàyè fún Ọlọrun.”

39. Àwọn kan ninu àwọn amòfin dá a lóhùn pé, “Olùkọ́ni, o wí ire!”

40. Láti ìgbà náà kò tún sí ẹni tí ó láyà láti bi í ní nǹkankan mọ́.

Ka pipe ipin Luku 20