Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Luku 20:23-31 BIBELI MIMỌ (BM)

23. Ṣugbọn ó ti mọ ẹ̀tàn wọn. Ó sọ fún wọn pé,

24. “Ẹ fi owó fadaka kan hàn mí.” Ó bá bi wọ́n léèrè pé, “Àwòrán ati àkọlé ta ni ti ara rẹ̀ yìí?”Wọ́n ní, “Ti Kesari ni.”

25. Ó bá wí fún wọn pé, “Tí ó bá rí bẹ́ẹ̀, ẹ fi ohun tí ó bá jẹ́ ti Kesari fún Kesari, kí ẹ sì fi ohun tí ó bá jẹ́ ti Ọlọrun fún Ọlọrun.”

26. Wọn kò lè mú ọ̀rọ̀ mọ́ ọn lẹ́nu lójú gbogbo eniyan. Ìdáhùn rẹ̀ yà wọ́n lẹ́nu, wọ́n bá dákẹ́.

27. Àwọn kan ninu àwọn Sadusi bá lọ sọ́dọ̀ rẹ̀. (Àwọn Sadusi ni wọn kò gbà pé òkú kan a tún máa jinde.) Wọ́n bi í pé,

28. “Olùkọ́ni, Mose pàṣẹ fún wa pé bí eniyan bá ní iyawo, bí ó bá kú láìní ọmọ, kí àbúrò rẹ̀ ṣú iyawo rẹ̀ lópó, kí ó ní ọmọ lórúkọ ẹ̀gbọ́n rẹ̀.

29. Àwọn tẹ̀gbọ́n-tàbúrò meje kan wà. Ekinni gbé iyawo, ó kú láìní ọmọ.

30. Bẹ́ẹ̀ náà ni ekeji.

31. Ẹkẹta náà ṣú u lópó. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn mejeeje ṣe, wọ́n kú láì ní ọmọ.

Ka pipe ipin Luku 20