Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Luku 20:1-7 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ní ọjọ́ kan, bí Jesu ti ń kọ́ àwọn eniyan lẹ́kọ̀ọ́ ninu Tẹmpili, tí ó ń waasu ìyìn rere fún wọn, àwọn olórí alufaa, àwọn amòfin, ati àwọn àgbà wá sọ́dọ̀ rẹ̀.

2. Wọ́n bi í pé, “Sọ fún wa irú àṣẹ tí o fi ń ṣe àwọn nǹkan wọnyi; ta ni ó sì fún ọ ní àṣẹ yìí?”

3. Ó dá wọn lóhùn pé, “Èmi náà yóo bi yín ní ọ̀rọ̀ kan, ẹ dá mi lóhùn.

4. Ìrìbọmi tí Johanu ń ṣe, láti ọ̀run wá ni, tabi láti ọ̀dọ̀ eniyan?”

5. Wọ́n ń bá ara wọn sọ pé, “Bí a bá sọ pé, ‘Láti ọ̀run ni,’ yóo bi wá pé, ‘Kí ló dé tí ẹ kò fi gbà á gbọ́?’

6. Bí a bá sọ pé, ‘Láti ọ̀dọ̀ eniyan ni,’ gbogbo àwọn eniyan yóo sọ wá ní òkúta pa, nítorí wọ́n gbà dájú pé wolii ni Johanu.”

7. Wọ́n bá dá a lóhùn pé, “A kò mọ ibi tí ó ti wá.”

Ka pipe ipin Luku 20