Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Luku 2:1-10 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ní àkókò náà, àṣẹ kan jáde láti ọ̀dọ̀ Kesari Augustu pé kí gbogbo ayé lọ kọ orúkọ wọn sinu ìwé ìjọba.

2. Èyí ni àkọsílẹ̀ ekinni tí wọ́n ṣe nígbà tí Kureniu jẹ́ gomina Siria.

3. Gbogbo àwọn eniyan bá lọ kọ orúkọ wọn sílẹ̀, ẹnìkọ̀ọ̀kan lọ sí ìlú ara rẹ̀.

4. Josẹfu náà gbéra láti Nasarẹti ìlú kan ní ilẹ̀ Galili, ó lọ sí ìlú Dafidi tí ó ń jẹ́ Bẹtilẹhẹmu, ní ilẹ̀ Judia, nítorí ẹbí Dafidi ni.

5. Ó lọ kọ orúkọ sílẹ̀ pẹlu Maria iyawo àfẹ́sọ́nà rẹ̀, tí ó lóyún, tí ó sì fẹ́rẹ̀ bímọ.

6. Ó wá yá nígbà tí wọ́n wà ní Bẹtilẹhẹmu, àkókò tó fún Maria láti bímọ.

7. Ó bá bí àkọ́bí rẹ̀ ọmọkunrin, ó fi ọ̀já wé e, ó tẹ́ ẹ sí ibùjẹ ẹran, nítorí kò sí àyè fún wọn ninu ilé èrò.

8. Ní àkókò náà, àwọn olùṣọ́-aguntan wà ní pápá, níbi tí wọn ń ṣọ́ aguntan wọn ní òru.

9. Angẹli Oluwa kan bá yọ sí wọn, ògo Oluwa tan ìmọ́lẹ̀ yí wọn ká. Ẹ̀rù bà wọ́n gan-an.

10. Ṣugbọn angẹli náà wí fún wọn pé, “Ẹ má bẹ̀rù mọ́, nítorí mo mú ìròyìn ayọ̀ ńlá fun yín wá, ayọ̀ tí yóo jẹ́ ti gbogbo eniyan.

Ka pipe ipin Luku 2