Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Luku 19:3-19 BIBELI MIMỌ (BM)

3. Ó fẹ́ rí Jesu kí ó mọ ẹni tí í ṣe. Ṣugbọn kò lè rí i nítorí ọ̀pọ̀ eniyan ati pé eniyan kúkúrú ni.

4. Ó bá sáré lọ siwaju, ó gun igi sikamore kan kí ó lè rí i, nítorí ọ̀nà ibẹ̀ ni Jesu yóo gbà kọjá.

5. Nígbà tí Jesu dé ọ̀gangan ibẹ̀, ó gbé ojú sókè, ó sọ fún un pé, “Sakiu, tètè sọ̀kalẹ̀, nítorí ọ̀dọ̀ rẹ ni mo gbọdọ̀ dé sí lónìí.”

6. Ni Sakiu bá sọ̀kalẹ̀, ó sì fi ayọ̀ gbà á lálejò.

7. Nígbà tí àwọn eniyan rí i, gbogbo wọn bẹ̀rẹ̀ sí kùn sí Jesu, wọ́n ní, “Lọ́dọ̀ ẹlẹ́ṣẹ̀ ni ó lọ wọ̀ sí!”

8. Sakiu bá dìde dúró, ó sọ fún Oluwa pé, “N óo pín ààbọ̀ ohun tí mo ní fún àwọn talaka. Bí mo bá sì ti fi ọ̀nà èrú gba ohunkohun lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni, mo ṣetán láti dá a pada ní ìlọ́po mẹrin.”

9. Jesu bá dá a lóhùn pé, “Lónìí yìí ni ìgbàlà wọ inú ilé yìí, nítorí ọmọ Abrahamu ni Sakiu náà.

10. Nítoí Ọmọ-Eniyan dé láti wá àwọn tí wọ́n sọnù kiri, ati láti gbà wọ́n là.”

11. Bí wọ́n ti ń gbọ́ ọ̀rọ̀ wọnyi, ó tún fi òwe kan bá wọn sọ̀rọ̀, nítorí ó súnmọ́ Jerusalẹmu, àwọn eniyan sí rò pé ó tó àkókò tí ìjọba Ọlọrun yóo farahàn.

12. Nítorí náà ó sọ fún wọn pé, “Ọkunrin ìjòyè pataki kan lọ sí ilẹ̀ òkèèrè, wọ́n fẹ́ fi jọba níbẹ̀ kí ó sì pada wálé lẹ́yìn náà

13. Ó bá pe àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀ mẹ́wàá, ó fún ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn ní owó wúrà kọ̀ọ̀kan. Ó ní, ‘Ẹ máa lọ fi ṣòwò kí n tó dé.’

14. Ṣugbọn àwọn ọmọ-ìbílẹ̀ ibẹ̀ kórìíra rẹ̀. Wọ́n bá rán ikọ̀ ṣiwaju rẹ̀ láti lọ sọ pé àwọn kò fẹ́ kí ọkunrin yìí jọba lórí àwọn!

15. “Nígbà tí ọkunrin yìí jọba tán, tí ó pada dé, ó bá ranṣẹ pe àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀ tí ó ti fún lówó, kí ó baà mọ èrè tí wọ́n ti jẹ.

16. Ekinni bá dé, ó ní, ‘Alàgbà, mo ti fi owó wúrà kan tí o fún mi pa owó wúrà mẹ́wàá.’

17. Oluwa rẹ̀ wí fún un pé, ‘O ṣeun, ọmọ-ọ̀dọ̀ rere. O ti ṣe olóòótọ́ ninu ohun kékeré. Mo fi ọ́ ṣe aláṣẹ lórí ìlú mẹ́wàá.’

18. Ekeji dé, ó ní, ‘Alàgbà, mo ti fi owó wúrà rẹ pa owó wúrà marun-un.’

19. Oluwa rẹ̀ wí fún òun náà pé, ‘Mo fi ọ́ ṣe aláṣẹ lórí ìlú marun-un.’

Ka pipe ipin Luku 19