Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Luku 19:13-26 BIBELI MIMỌ (BM)

13. Ó bá pe àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀ mẹ́wàá, ó fún ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn ní owó wúrà kọ̀ọ̀kan. Ó ní, ‘Ẹ máa lọ fi ṣòwò kí n tó dé.’

14. Ṣugbọn àwọn ọmọ-ìbílẹ̀ ibẹ̀ kórìíra rẹ̀. Wọ́n bá rán ikọ̀ ṣiwaju rẹ̀ láti lọ sọ pé àwọn kò fẹ́ kí ọkunrin yìí jọba lórí àwọn!

15. “Nígbà tí ọkunrin yìí jọba tán, tí ó pada dé, ó bá ranṣẹ pe àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀ tí ó ti fún lówó, kí ó baà mọ èrè tí wọ́n ti jẹ.

16. Ekinni bá dé, ó ní, ‘Alàgbà, mo ti fi owó wúrà kan tí o fún mi pa owó wúrà mẹ́wàá.’

17. Oluwa rẹ̀ wí fún un pé, ‘O ṣeun, ọmọ-ọ̀dọ̀ rere. O ti ṣe olóòótọ́ ninu ohun kékeré. Mo fi ọ́ ṣe aláṣẹ lórí ìlú mẹ́wàá.’

18. Ekeji dé, ó ní, ‘Alàgbà, mo ti fi owó wúrà rẹ pa owó wúrà marun-un.’

19. Oluwa rẹ̀ wí fún òun náà pé, ‘Mo fi ọ́ ṣe aláṣẹ lórí ìlú marun-un.’

20. “Ẹkẹta dé, ó ní, ‘Alàgbà, owó wúrà rẹ nìyí, aṣọ ni mo fi dì í, mo sì fi pamọ́,

21. nítorí mo bẹ̀rù rẹ. Nítorí òǹrorò eniyan ni ọ́. Níbi tí o kò fi nǹkan sí ni o máa ń wá a sí; níbi tí o kò fúnrúgbìn sí ni o ti máa ń kórè.’

22. Oluwa rẹ̀ wí fún un pé, ‘Ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ gan-an ni n óo fi ṣe ìdájọ́ rẹ, ìwọ ọmọ-ọ̀dọ̀ burúkú yìí. O mọ̀ pé níbi tí n kò fi nǹkan sí ni mo máa ń wá a sí, ati pé níbi tí n kò fúnrúgbìn sí ni mo ti máa ń kórè.

23. Kí ni kò jẹ́ kí o lọ fi owó mi pamọ́ sí banki, tí ó fi jẹ́ pé bí mo ti dé yìí, ǹ bá gbà á pẹlu èlé?’

24. “Ó bá sọ fún àwọn tí ó dúró níbẹ̀ pé, ‘Ẹ gba owó wúrà náà ní ọwọ́ rẹ̀, kí ẹ fún ẹni tí ó ní owó wúrà mẹ́wàá.’

25. Wọ́n bá dá a lóhùn pé, ‘Alàgbà, ṣebí òun ti ní owó wúrà mẹ́wàá!’

26. Ó wá sọ fún wọn pé, ‘Gbogbo ẹni tí ó bá ní ni a óo tún fún sí i. Ọwọ́ ẹni tí kò sì ní, ni a óo ti gba ìba díẹ̀ tí ó ní!

Ka pipe ipin Luku 19