Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Luku 19:1-6 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Nígbà tí Jesu dé Jẹriko, ó ń la ìlú náà kọjá.

2. Ọkunrin kan wà tí ó ń jẹ́ Sakiu. Òun ni olórí agbowó-odè níbẹ̀. Ó sì lówó.

3. Ó fẹ́ rí Jesu kí ó mọ ẹni tí í ṣe. Ṣugbọn kò lè rí i nítorí ọ̀pọ̀ eniyan ati pé eniyan kúkúrú ni.

4. Ó bá sáré lọ siwaju, ó gun igi sikamore kan kí ó lè rí i, nítorí ọ̀nà ibẹ̀ ni Jesu yóo gbà kọjá.

5. Nígbà tí Jesu dé ọ̀gangan ibẹ̀, ó gbé ojú sókè, ó sọ fún un pé, “Sakiu, tètè sọ̀kalẹ̀, nítorí ọ̀dọ̀ rẹ ni mo gbọdọ̀ dé sí lónìí.”

6. Ni Sakiu bá sọ̀kalẹ̀, ó sì fi ayọ̀ gbà á lálejò.

Ka pipe ipin Luku 19