Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Luku 18:31-43 BIBELI MIMỌ (BM)

31. Ó mú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mejila lọ sápá kan, ó sọ fún wọn pé, “Ṣé ẹ rí Jerusalẹmu tí à ń gòkè lọ yìí, gbogbo ohun tí àwọn wolii kọ nípa Ọmọ-Eniyan ni yóo ṣẹ.

32. Nítorí a óo fi í lé àwọn tí kì í ṣe Juu lọ́wọ́. Wọn óo fi ṣe ẹ̀sín, wọn óo fi àbùkù kàn án, wọn óo tutọ́ sí i lára.

33. Nígbà tí wọ́n bá nà án tán, wọn óo sì pa á. Ṣugbọn ní ọjọ́ kẹta, yóo jí dìde.”

34. Ṣugbọn ohun tí ó sọ kò yé wọn. Ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ náà sápamọ́ fún wọn. Wọn kò mọ ohun tí ó ń sọ.

35. Nígbà tí Jesu súnmọ́ etí ìlú Jẹriko, afọ́jú kan wà lẹ́bàá ọ̀nà, ó jókòó, ó ń ṣagbe.

36. Nígbà tí ó gbọ́ tí ọ̀pọ̀ eniyan ń kọjá lọ, ó wádìí ohun tí ó dé.

37. Wọ́n sọ fún un pé, “Jesu ará Nasarẹti ní ń kọjá.”

38. Ni alágbe náà bá pariwo pé, “Jesu, ọmọ Dafidi, ṣàánú mi!”

39. Àwọn tí ó ń kọjá lọ ń bá a wí pé kí ó panu mọ́. Ṣugbọn ńṣe ni ó túbọ̀ ń kígbe pé, “Ọmọ Dafidi, ṣàánú mi.”

40. Jesu bá dúró, ó ní kí wọ́n lọ fà á lọ́wọ́ wá sọ́dọ̀ òun. Nígbà tí ó dé, Jesu bi í pé,

41. “Kí ni o fẹ́ kí n ṣe fún ọ?”Ó dáhùn pé, “Alàgbà, mo fẹ́ tún ríran ni!”

42. Jesu sọ fún un pé, “Ǹjẹ́, ríran. Igbagbọ rẹ mú ọ lára dá.”

43. Lójú kan náà ó sì tún ríran, ó bá ń tẹ̀lé Jesu, ó ń yin Ọlọrun lógo. Nígbà tí gbogbo àwọn eniyan rí i, wọ́n fi ìyìn fún Ọlọrun.

Ka pipe ipin Luku 18