29. Ó bá sọ fún wọn pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé kò sí ẹni tí ó fi ilé, iyawo, arakunrin, òbí tabi ọmọ sílẹ̀, nítorí ti ìjọba Ọlọrun,
30. tí kò ní rí ìlọ́po-ìlọ́po gbà ní ayé yìí, yóo sì ní ìyè ainipẹkun ní ayé tí ń bọ̀.”
31. Ó mú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mejila lọ sápá kan, ó sọ fún wọn pé, “Ṣé ẹ rí Jerusalẹmu tí à ń gòkè lọ yìí, gbogbo ohun tí àwọn wolii kọ nípa Ọmọ-Eniyan ni yóo ṣẹ.
32. Nítorí a óo fi í lé àwọn tí kì í ṣe Juu lọ́wọ́. Wọn óo fi ṣe ẹ̀sín, wọn óo fi àbùkù kàn án, wọn óo tutọ́ sí i lára.
33. Nígbà tí wọ́n bá nà án tán, wọn óo sì pa á. Ṣugbọn ní ọjọ́ kẹta, yóo jí dìde.”
34. Ṣugbọn ohun tí ó sọ kò yé wọn. Ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ náà sápamọ́ fún wọn. Wọn kò mọ ohun tí ó ń sọ.
35. Nígbà tí Jesu súnmọ́ etí ìlú Jẹriko, afọ́jú kan wà lẹ́bàá ọ̀nà, ó jókòó, ó ń ṣagbe.
36. Nígbà tí ó gbọ́ tí ọ̀pọ̀ eniyan ń kọjá lọ, ó wádìí ohun tí ó dé.
37. Wọ́n sọ fún un pé, “Jesu ará Nasarẹti ní ń kọjá.”
38. Ni alágbe náà bá pariwo pé, “Jesu, ọmọ Dafidi, ṣàánú mi!”