Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Luku 17:7-16 BIBELI MIMỌ (BM)

7. “Bí ẹnìkan ninu yín bá ní iranṣẹ kan tí ó lọ roko tabi tí ó lọ tọ́jú àwọn aguntan, tí ó bá wọlé dé láti inú oko, ǹjẹ́ ohun tí yóo sọ fún un ni pé kí ó tètè wá jókòó kí ó jẹun?

8. Àbí yóo sọ fún iranṣẹ náà pé, ‘Tọ́jú ohun tí n óo jẹ. Ṣe gírí kí o gbé oúnjẹ fún mi. Nígbà tí mo bá jẹ tán, tí mo mu tán, kí o wá jẹ tìrẹ.’

9. Ǹjẹ́ ó jẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ ọmọ-ọ̀dọ̀ nítorí pé ó ṣe ohun tí ó níláti ṣe?

10. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni kí ẹ ṣe. Nígbà tí ẹ bá ti ṣe ohun gbogbo tí a pa láṣẹ fun yín tán, kí ẹ sọ pé, ‘Ọmọ-ọ̀dọ̀ ni a jẹ́. Ohun tí a ṣe kì í ṣe ọ̀rọ̀ ọpẹ́. Ohun tí ó yẹ kí á ṣe ni a ti ṣe.’ ”

11. Bí Jesu ti ń bá ìrìn àjò rẹ̀ lọ sí Jerusalẹmu, ó ń gba ààrin Samaria ati Galili kọjá.

12. Bí ó tí ń wọ abúlé kan lọ, àwọn ọkunrin adẹ́tẹ̀ mẹ́wàá kan pàdé rẹ̀. Wọ́n dúró lókèèrè,

13. wọ́n kígbe pé, “Ọ̀gá, Jesu, ṣàánú wa.”

14. Nígbà tí ó rí wọn, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ lọ fi ara yín hàn alufaa.”Bí wọ́n ti ń lọ, ara wọn bá dá.

15. Nígbà tí ọ̀kan ninu wọn rí i pé ara òun ti dá, ó pada, ó ń fi ìyìn fún Ọlọrun pẹlu ohùn gíga.

16. Ó bá dojúbolẹ̀ níwájú Jesu, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀. Ará Samaria ni.

Ka pipe ipin Luku 17