Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Luku 17:20-35 BIBELI MIMỌ (BM)

20. Àwọn Farisi bi Jesu nípa ìgbà tí ìjọba Ọlọrun yóo dé. Ó dá wọn lóhùn pé, “Dídé ìjọba Ọlọrun kò ní àmì tí a óo máa fẹjú kí á tó ri pé ó dé tabi kò dé.

21. Kì í ṣe ohun tí àwọn eniyan yóo máa sọ pé, ‘Ó wà níhìn-ín’ tabi ‘Ó wà lọ́hùn-ún.’ Nítorí ìjọba Ọlọrun wà láàrin yín.”

22. Ó wá sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn pé, “Ọjọ́ ń bọ̀ tí ẹ óo fẹ́ rí ọ̀kan ninu ọjọ́ dídé Ọmọ-Eniyan, ṣugbọn ẹ kò ní rí i.

23. Wọn yóo máa sọ pé, ‘Wò ó níhìn-ín’ tabi, ‘Wò ó lọ́hùn-ún’. Ẹ má lọ, ẹ má máa sáré tẹ̀lé wọn kiri.

24. Nítorí bí mànàmáná tíí kọ yànràn, tíí sìí tan ìmọ́lẹ̀ láti òkè délẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni Ọmọ-Eniyan yóo rí ní ọjọ́ tí ó bá dé.

25. Ṣugbọn dandan ni pé kí ó kọ́kọ́ jìyà pupọ, kí ìran yìí sì kẹ̀yìn sí i.

26. Àní bí ó ti rí ní àkókò Noa, bẹ́ẹ̀ ni yóo rí nígbà tí Ọmọ-Eniyan bá dé.

27. Nítorí ní àkókò Noa, wọ́n ń jẹ, wọ́n ń mu, wọ́n ń gbeyawo, wọ́n ń fi ọmọ fọ́kọ, títí di ọjọ́ tí Noa fi wọ inú ọkọ̀, ìkún-omi bá dé, ó bá pa gbogbo wọn rẹ́.

28. Bákan náà ni ó rí ní àkókò ti Lọti. Wọ́n ń jẹ, wọ́n ń mu, wọ́n ń rà, wọ́n ń tà, wọ́n ń fúnrúgbìn, wọ́n ń kọ́lé,

29. títí di ọjọ́ tí Lọti fi jáde kúrò ní Sodomu, tí Ọlọrun fi rọ̀jò iná ati òkúta gbígbóná lé wọn lórí, tí ó pa gbogbo wọn rẹ́.

30. Bẹ́ẹ̀ ni yóo rí ní ọjọ́ tí Ọmọ-Eniyan bá yọ dé.

31. “Ní ọjọ́ náà, bí ẹnìkan bá wà lórí ilé, tí àwọn nǹkan rẹ̀ wà ninu ilé, kí ó má sọ̀kalẹ̀ lọ kó o. Bákan náà ni ẹni tí ó bá wà lóko kò gbọdọ̀ pada sílé.

32. Ẹ ranti iyawo Lọti

33. Ẹni tí ó bá ń wá ọ̀nà láti gba ẹ̀mí rẹ̀ là, yóo pàdánù rẹ̀. Ẹni tí ó bá pàdánù ẹ̀mí rẹ̀, yóo gbà á là.

34. Mo sọ fun yín, ní ọjọ́ náà, eniyan meji yóo sùn lórí ibùsùn kan, a óo mú ọ̀kan, a óo fi ekeji sílẹ̀.

35. Àwọn obinrin meji yóo máa lọ ògì, a óo mú ọ̀kan, a óo fi ekeji sílẹ̀. [

Ka pipe ipin Luku 17