Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Luku 15:26-32 BIBELI MIMỌ (BM)

26. Ó pe ọmọde kan, ó wádìí ohun tí ń ṣẹlẹ̀.

27. Ọmọ yìí bá sọ fún un pé, ‘Àbúrò rẹ dé, baba rẹ sì pa mààlúù tí ó sanra, ó se àsè nítorí tí àbúrò rẹ pada dé ní alaafia.’

28. Inú bí èyí ẹ̀gbọ́n, ó bá kọ̀, kò wọlé. Ni baba rẹ̀ bá jáde lọ láti lọ bẹ̀ ẹ́.

29. Ṣugbọn ó sọ fún baba rẹ̀ pé, ‘Wo ati ọdún tí mo ti ń sìn ọ́, n kò dá àṣẹ rẹ kọjá rí; sibẹ o kò fún mi ni ọmọ ewúrẹ́ kan kí n fi ṣe àríyá pẹlu àwọn ọ̀rẹ́ mi rí.

30. Ṣugbọn nígbà tí ọmọ rẹ yìí dé, àpà ara rẹ̀, tí ó ti run ogún rẹ̀ sọ́dọ̀ àwọn aṣẹ́wó, o wá pa mààlúù tí ó sanra fún un.’

31. Baba rẹ̀ dá a lóhùn pé, ‘Ọmọ mi, ìwọ wà lọ́dọ̀ mi nígbà gbogbo, gbogbo ohun tí mo ní, tìrẹ ni.

32. Ó yẹ kí á ṣe àríyá, kí á sì máa yọ̀, nítorí àbúrò rẹ yìí ti kú, ó sì tún yè, ó ti sọnù, a sì tún rí i.’ ”

Ka pipe ipin Luku 15